Monisọla Saka
Obinrin ajijagbara ilẹ wa kan, Aisha Yesufu, ti sọrọ si iyawo Aarẹ orilẹ-ede yii, Aisha Buhari, fun iwa ta ni yoo mu mi to hu gẹgẹ bo ṣe paṣẹ pe ki wọn sọ ọdọmọkunrin kan, Aminu Mohammed, si atimọle lori ọrọ odi ti wọn lo sọ si i lori ẹrọ ayelujara.
Muhammed, ọdọmọkunrin akẹkọọ to wa nipele to kẹyin lẹka ẹkọ imọ nipa ayika (Environmental Management and Toxicology), nileewe giga Federal University Dutse, ipinlẹ Jigawa, ni wọn lo fi ede Hausa kọ ọrọ kan sabẹ fọto Aisha Buhari lori ẹrọ alatagba Twitter rẹ ninu oṣu Kẹfa, ọdun yii pe, “iya ti tobi si i pẹlu owo awọn araalu to n jẹ”.
Alaroye gbọ pe ọrọ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ tawọn olukọ Fasiti ilẹ wa (ASUU) gun le nigba naa, tawọn ijọba si kọ ti wọn o ṣe nnkan kan si i lo mu ki akẹkọọ naa sọrọ naa lati fi ẹdun ọkan rẹ han. Ohun ti wọn lọmọkunrin naa ni lọkan ni pe, owo to yẹ ki wọn fi yanju aawọ laarin ijọba atawọn ẹgbẹ ASUU loun fi n ṣe ara rindin, tiya si n jẹ awọn akẹkọọ gẹgẹ bi wọn ṣe n fẹsẹ gbalẹ kiri nigba ti wọn ko ri ileewe lọ.
Ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun (23) ọhun ni wọn lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, DSS lọọ gbe ninu ọgba ileewe wọn ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla yii. Wọn ni wọn kọkọ fi lulu da batani si i lara, lẹyin naa ni wọn fi panpẹ ofin gbe e lọ si itimọle.
Eyi lo mu ki Aisha Yesufu, obinrin ajijagbara to ja fitafita lori ọrọ awọn akẹkọọ-binrin Chibok tawọn Boko Haram ji gbe lọjọsi, ati lasiko ọrọ ENDSARS to waye ni nnkan bii ọdun meji sẹyin bayii, gba ori ẹrọ ayelujara YouTube ẹ lọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun yii, lati bu ẹnu atẹ lu iwa to ṣapejuwe bi ifọwọ-ọla-gba-ni-loju ti wọn hu si ọmọkunrin naa, o ni iwa ti ko bofin mu rara ni.
O tẹsiwaju pe awọn ọmọ ilẹ Naijiria bii ọgọfa miliọnu ni ijọba Buhari yii ti ko sinu iṣẹ ati oṣi.
Yesufu ni, “Oju gba mi ti fun Aisha Buhari, niṣe lo yẹ ko dọwọ boju. Iwa ika ti ko ba ofin mu rara leyi. Ọkọ ẹ ti ju ida mẹtalelọgọta (63%) awọn ọmọ Naijiria sinu iṣẹ ati iya ti ko mọ niwọnba, ti wọn n ba iyẹn yi lọwọ na. Ṣe loootọ kọ waa ni pe awodi wọn n jẹun epe sanra, ṣe òógùn awọn ọmọ Naijiria kọ lo mu un tobi gẹgẹ bi wọn ṣe wi? Awọn ti ju ara wọn sinu agbami ọla ati ọrọ̀ ni tiwọn. Ta loun, bawo ni tiẹ ṣe jẹ to fi maa ni ki wọn lọọ fi panpẹ ofin gbe eeyan kan nitori pe wọn lo ti jẹ ọrọ̀ awọn alaini?
“Nigba to mọ pe agbara oun to bayii, ki lo de ti ko ti lo o lati gba awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa nigbekun silẹ?”
Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ti wọn wa lori ayelujara Twitter ni wọn ti n sọrọ latigba naa, nigba tawọn kan n gbara ta lori aṣẹ ti wọn ni iyawo Aarẹ pa pe ki DSS maa ko gbogbo ẹni to ba sọrọ ta ko oun, awọn mi-in n bu ẹnu atẹ lu oun ati ijọba ọkọ ẹ, to fi mọ awọn DSS pe o rọrun lati tọpinpin eeyan pẹlu ẹrọ ayelujara ẹ ki wọn ri i mu, ṣugbọn o ṣoro lati ri awọn ti wọn n da omi alaafia orilẹ-ede yii ru lati ọjọ yii wa.
Ẹrin atawada kẹrikẹri lawọn eeyan mi-in si n ṣe, wọn lawọn o mọ boya DSS n ri awọn nibi tawọn ti n tẹ ọrọ sori ẹrọ ayelujara lọwọ bayii, nitori awọn o fẹ wahala ijọba to maa n yara gbe ẹni tipa wọn ka.