Monisọla Saka
Awọn afurasi ole wan ṣanṣi meji kan lọwọ ileeṣẹ to n ri si igbokegbodo ọkọ, LASTMA, ipinlẹ Eko, tẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ti Ọlọrun si lo wọn lati gba obinrin kan to ti lugbadi iṣẹ buruku ọwọ wọn silẹ.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ naa, Adebayọ Taofiq, fi sita, awọn oṣiṣẹ LASTMA ti wọn maa n duro sibi Presbyterian Church, agbegbe Yaba, nipinlẹ Eko, ni Ọlọrun fi ṣe angẹli obinrin ọhun.
Ninu atẹjade naa ni wọn ti ni ọga agba ajọ LASTMA, Bọlaji Ọrẹagba, sọ pe, “Awọn oṣiṣẹ wa lẹnu iṣẹ pẹlu iranlọwọ awọn ero to n lọ to n bọ ni wọn le ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan ti nọmba rẹ jẹ FST 60 RJ, lẹyin ti wọn n gbọ ariwo, ‘ole, ajinigbe, gbọmọgbọmọ’ ti obinrin kan to jokoo si ọwọ ẹyin ninu ọkọ naa n pa bi ọkọ naa ṣe n sọkalẹ lati ori biriiji Jibowu si Yaba.
Bi wọn ṣe ri ọkọ naa da duro ni wọn sare gba awakọ ati obinrin to jokoo ti i niwaju mu ki wọn too poora mọ aarin ero, ti obinrin to n pariwo gbọmọgbọmọ si sare sọ kalẹ ninu ọkọ lati sọ ohun ti oju ẹ ri.
“O ṣalaye pe ni kete ti oun wọkọ to n lọ si Apapa lati agbegbe Maryland, ni obinrin to jokoo sẹgbẹẹ awakọ niwaju ti kọkọ fi ogboju gba foonu atawọn nnkan olowo iyebiye mi-in lọwọ oun, nitori bẹẹ loun ṣe sare pariwo ole nigba tawọn de aarin ero ti wọn le gba oun kalẹ, nigba toun ri i pe awọn ole ‘wan ṣansi’ ti wọn maa n ja ero inu ọkọ lole nnkan ini wọn, ti wọn yoo si lọọ ja tọhun sibi to ba wu wọn lẹyin ti wọn ba ṣọṣẹ tan ni wọn.
Obinrin to jokoo ti onimọto niwaju, Joy, ṣalaye pe awakọ ọhun torukọ ẹ n jẹ Monday Amhe, lo mu oun mọ iṣẹ apanilẹkunjaye naa.
Awọn mejeeji yii ni awọn oṣiṣẹ LASTMA ti fa le awọn agbofinro teṣan Sabo lọwọ fun iwadii to peye”.
Ọga agba awọn LASTMA waa rọ awọn eeyan lati ṣọra pẹlu iru ọkọ ti wọn yoo maa wọ ti wọn ba n jade lọ, paapaa ju lọ ninu oṣu disẹmba ta a n wo lọọọkan yii, gẹgẹ bo ṣe jẹ pe inu pọpọṣinṣin ọdun bayii lawọn oniṣẹ ibi yẹn maa ṣọṣẹ ju.