Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ni awọn janduku ẹgbẹ oṣelu PDP kọ lu patako ipolongo ẹgbẹ oṣelu to n sejọba lọwọ, All Progressives Congress (APC), lagbegbe Ode-Alausa, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti ọpọ si fara pa nibi akọlu naa.
ALAROYE gbọ pe awọn agba ẹgbẹ oṣelu PDP meji kan ti wọn jẹ alatilẹyin si Dokita Bukọla Saraki, ti wọn tun jẹ adari ẹgbẹ oṣelu naa ni Kwara, Dokita Giwa Lukman ati Alaaji Uthman, ni wọn ṣe onigbọwọ akọlu naa.
Awọn janduku ọhun ba gbogbo patako ipolongo to wa ni agbegbe naa jẹ, wọn si sa awọn eniyan to n gbe ni agbegbe naa ti wọn n lọ jẹẹjẹ wọn ladaa, ti ọpọ si ti dero ileewosan bayii. A gbọ pe ki i ṣe igba akọkọ niyi ti awọn janduku naa yoo ṣe ba patako ipolongo APC ipinlẹ Kwara jẹ, wọn ni wọn ti kọkọ ṣe bẹẹ ni agbegbe Ubandawaki, niluu Ilọrin, yii kan naa. Awọn agba ẹgbẹ APC ti waa rọ awọn ẹṣọ alaabo lati gbe igbesẹ ofin lori awọn janduku ọhun tori pe o ti di baraku fun wọn ki wọn maa huwa janduku.