Faith Adebọla
Gbajugbaja olori Fuji kan, Kọlinton Ayinla, lo kọ ọ lorin ninu awo rẹ kan bayii pe “Ẹni ti ko kọṣẹ NEPA, to lọọ n gun opo ina, ọjọ iku ẹ lo n fi n ṣere.” Ọrọ yii ti ja si ootọ fun ọkunrin kan ti wọn porukọ ẹ ni Ezekiel yii o, niṣe lọkunrin naa fẹẹ ji waya ina ẹlẹntiriiki ge, lo ba pọn opoona lọ, o gun un doke, o si yọ irinṣẹ ti wọn fi n ge waya rẹ jade, ṣugbọn nibi to ti n ṣiṣẹ laabi ọhun lọwọ, ọkan ninu waya ti ina ẹlẹntiriiki wa lara ẹ ba ole yii, lo ba gan mọbẹ!
Oru mọju ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ karun-un, oṣu Kejila yii, niṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Utako, niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa.
Onimọto kan to porukọ ara ẹ ni Hassan sọ fun ajọ akoroyinjọ ilẹ wa, (NAN), pe: “Laaarọ kutu yii, niṣe la kan n wo oku ọkunrin to n jẹ Ezekiel yii loke nibi to gan mọna si. Waya ina lo fẹẹ ji ge, waya high tension ti Abuja Electricity Distribution Company.
“Loru, ni nnkan bii aago mẹta, a gbọ ti waya ina dun, to si ṣana para-para, a ro pe atẹgun lo gbe waya kọ lu ara wọn ni, ṣugbọn a tun gburoo ẹnikan to lọgun oro, ko sẹni to jade o, tori asiko yii lewu lati rin loru. Afi bo ṣe di ilẹ mọ ta a ri i pe ole yii ni ina gbe.
“Ti ko ba jẹ pe a ri pulaya (plier) ati tọọṣi, atawọn irinṣẹ to ja bọ lọwọ ẹ nigba tina gbe e ni, niṣe la kọkọ ro pe o gun opoona naa lati lọọ pokunso ni, ṣugbọn awọn nnkan ta a ri lo jẹ ka mọ pe ole ni, waya lo fẹẹ ji ge, kọwọ palaba rẹ too segi.”
Ṣugbọn Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Abuja, Joseph Adeh, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o si tun sọ pe loootọ ni ina gbe ọkunrin naa, ṣugbọn ko ku, o kan fara gbọgbẹ gidi ni. Wọn lo wa nileewosan kan ti wọn gbe e lọ, tori bo ṣe fara ko ina naa ni ina mọnamọna ku. Wọn lo ṣi wa ni ba-a-ku-ba-a-ye nileewosan ijọba kan.