Loootọ ni wọn maa n sọ pe orukọ n ro’ni, ṣugbọn ọrọ ti ọkunrin ti wọn n pe ni Ayọmide Moses yii ko ri bẹẹ o, dipo ayọ, ibanujẹ ati ipayinkeke lo maa n ṣẹlẹ nibikibi ti toun ba gba kọja, tori iṣẹ oro lo n fibọn ọwọ ẹ ṣe, bo ṣe n digun jale lo n paayan, kọwọ palaba ẹ too segi lopin ọsẹ to kọja.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, to fọrọ yii to Alaroye leti lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kejila yii, o ni ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ Kọkanla, oṣu yii, lọwọ ba afurasi ọdaran naa.
Abilekọ kan, Basirat Anibiire, lo n fi ẹrọ POS ṣiṣẹ aje ninu ṣọọbu rẹ nirọlẹ ọjọ Sannde naa, oun atọmọ rẹ, ọmọọdun meje, ni wọn jọ wa nibẹ titi di nnkan bii aago meje aṣaalẹ ti wọn ti fẹẹ ṣiwọ laduugbo Fadahunsi Ijoko, lagbegbe Agbado, nijọba ibilẹ Ifọ, ipinlẹ Ogun.
Wọn ni bi obinrin naa ṣe n palẹkun ṣọọbu ọhun de lawọn afurasi ọdaran yii gun ọkada de ọdọ ẹ, mẹta ni wọn, meji ninu wọn bọọlẹ lori ọkada, wọn ba bẹrẹ si i ja a lole.
Wọn lobinrin yii dọgbọ sa asala fẹmi-in, ṣugbọn atakoro wọnu ado, ko ribi mu ọmọ ẹ wọ ọ, ọwọ awọn adigunjale tẹ ọmọ naa, ni wọn ba n wọ ọmọọlọmọ lọ sori ọkada wọn, bẹẹ lọmọ ọhun figbe ta, ara abiyamọ yii ko si gba a, lo ba tun sare waa bẹ wọn pe ki wọn gba ohunkohun ti wọn ba fẹ, ki wọn ma gbe ọmọ oun lọ. Eyi lo si mu kawọn apamọlẹkun-ẹda yii gba baagi to kowo ọja rẹ si lọwọ ẹ, ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (N400,000) ni wọn lo wa ninu baagi ọhun, wọn si tun gba foonu ẹ, ni wọn ba yọnda ọmọ ẹ fun un, wọn ta mọ ọkada wọn, wọn fere ge e.
Bi wọn ṣe n sa lọ lobinrin yii figbe ta, lo n keboosi ‘ole, ole’, bẹẹ lọmọ ẹ n sunkun yọbọ bi wọn ṣe n gbara yilẹ, eyi lo mu kawọn gende adugbo naa jade, ni wọn ba tọpasẹ awọn ole yii lọ, awọn kan si tun kan si teṣan ọlọpaa lori aago. Kia lawọn ọmọọṣẹ SP Awoniyi Adekunle to jẹ DPO ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Agbado naa debẹ, ṣugbọn ki wọn too debẹ, awọn ole yii ti yinbọn lati fi ṣeruba awọn bọisi to n lepa wọn ọhun, ibọn naa si ba Qudus Popoọla, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, oju-ẹsẹ lo ku.
Wọn lẹnikan to n jẹ Oluwaṣeun Falẹyẹ, atawọn mi-in lara awọn bọisi ọhun fara pa pẹlu, wọn ti ko wọn lọọ sileewosan, nibi ti wọn ti n gba itọju pajawiri.
Amọ ṣa, awọn ọlọpaa ri ọkan ninu awọn adigunjale yii, wọn ni Moses Ayọmide yii ja bọ lori ọkada nigba ti wọn n sa lọ, ni wọn ba ko ṣẹkẹṣẹkẹ si i lọwọ, o dero ahamọ.
Wọn ti yọnda oku Qudus fawọn mọlẹbi ẹ ki wọn le lọọ sin-in nilana Musulumi.
Iwadii ti n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle. ṣe paṣẹ, wọn lafurasi yii n ran awọn ọtẹlẹmuyẹ lọwọ lẹnu iwadii wọn, awọn agbofinro si ti n fimu finlẹ lati wa awọn ẹmẹwa Moses yii lawaari, ki gbogbo wọn le fara han niwaju adajọ.
CAPTION