Wọn ti mu Serkin Fulani Kwara, wọn lo mọ nipa ijinigbe to n ṣẹlẹ nipinlẹ naa

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Titi di bi a e n k iroyin yii, ahamọ ọgba ẹwọn Oke-Kura, niluu Ilọrin, ni Serkin Fulani ipinlẹ Kwara, Alaaji Abdullahi Adamu, Gamala, wa bayii, wọn lo mọ nipa gbogbo awọn ijinigbe to n waye nipinlẹ naa.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni ẹnikan ti ko fẹ ka darukọ oun fi to ALAROYE leti pe o ti to bii ọṣẹ meji sẹyin ti Serkin Fulani ipinlẹ naa pẹlu awọn afurasi ajinigbe yooku rẹ ti wa ni ahamọ ọgba ẹwọn Oke-Kura, lori ẹsun pe o lọwọ ninu bi wọn ṣe ji Arakunrin kan, Abubakar Ahmed, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, gbe, ti wọn si gba a mu inkun pẹlu awọn ẹri to daju. O tẹsiwaju pe lati igba ti ọwọ ti tẹ Serikin Fulani yii ni ko ti si ẹsun ijinigbe niluu Ilọrin ati gbogbo agbegbe rẹ mọ, eyi tumọ si pe Adamu gan-an  ni agbodegba fun awọn ajinigbe ni Kwara.

Awọn araalu wa n rọ ijọba Kwara, labẹ iejọba Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, lati jẹ ki idajọ ododo waye lori Adamu atawọn ajinigbe ẹgbẹ rẹ, ki gomina fihan pe loootọ gomina mẹkunnu, gomina araalu ni oun, ki wọn ma fi ẹsẹ ra ẹjọ naa mọlẹ, tori pe ko yẹ ki ẹlẹẹ lọ laijiya, ati pe ki alaafia le maa jọba ni Kwara, nitori ilu alaafia ni gbogbo eeyan mọ ipinlẹ naa si.

 O fi kun un pe oniruuru ẹsun iwa ọdaran ni wọn ti n mu Adamu fun lati bii ọjọ pipẹ, ugbọn ofin ijọba ko ri i mu.

Leave a Reply