Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Obinrin arinrin-ajo kan ti ori ko yọ lọwọ awọn ajinigbe nipinlẹ Ọṣun ti sọ ohun ti oju rẹ ri ati bo ṣe bọ lọwọ wọn.
Funmilayọ Adejumọ ṣalaye fawọn oniroyin lori foonu pe loju ọna Ileṣa si Akurẹ ni awọn ti ko sọwọ awọn ajinigbe lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu Kejila, ọdun yii.
Adejumọ ṣalaye pe ilu Akurẹ lawọn n lọ, nigba ti awọn de ilu Iwaraja, ni awọn ri i ti awọn kan gbegi di ọna, awọn ọlọpaa lawọn ro pe wọn wa nibẹ ti dẹrẹba awọn fi duro.
O ni, “Bi dẹrẹba wa ṣe duro, to si ri i pe awọn ajinigbe lawọn ti wọn da wa duro ni oun atawọn ọkunrin ti wọn wa ninu bọọsi ti sa wọnu igbo.
“Awọn ajinigbe yẹn yinbọn sọna ibi ti awọn ọkunrin yẹn sa gba lọ ki wọn too pada sidii bọọsi ti a wa. Wọn mu emi atawọn obinrin meji ti a ku nibẹ wọnu igbo.
“Odidi wakati meji la fi rin ninu igbo lalẹ ọjọ naa ko too di pe a de ibi kan ti wọn n lo. Wọn ko fun wa lounjẹ lalẹ ọjọ naa, aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ni wọn too fun wa ni gaari ati omi. Wọn gba foonu mi, wọn si beere pe ta ni mọlẹbi mi tawọn le pe lati beere owo itusilẹ.
“Nigba to di alẹ ọjọ Mọnde, wọn tun ko awọn obinrin meji mi-in wa sọdọ wa, wọn si sọ pe ka bẹrẹ si i rin lọ ninu igbo. Lojiji ni awọn ajinigbe mẹtẹẹta ti wọn wa lọdọ wa wọnu igbo kan lati ṣọdẹ ẹran lọ, wọn si fi awa maraarun silẹ
“Nigba ti mo ri i pe wọn ko de laarin ogun iṣẹju, mo pinnu lati sa wọnu igbo kijikiji kan lọ. Lẹyin wakati mẹrin ti mo ti n rin ninu igbo ni mo de abule kan, mo si ri awọn ọkunrin meji kan, awọn ni wọn juwe ọfiisi awọn Amọtẹkun fun mi n’ijọba ibilẹ Oriade.
“Mo ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn Amọtẹkun ti mo ba nibẹ, ọkan ninu wọn fun mi ni owo ti mo fi wọ mọto pada sọdọ awọn mọlẹbi mi.”
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun l’Ọṣun, Amitolu Shittu, ṣalaye pe awọn ikọ oun ti lọ sinu igbo ọhun lati le gba awọn to ku.