Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn figilante to wa l’Akoko ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣawari oku ọkunrin oniṣowo kan to ku sinu igbekun awọn ajinigbe lọsẹ to kọja yii.
ALAROYE gbọ pe ọkunrin ọmọ Ibo ọhun ati iyawo rẹ ti wọn fi ilu Ugbe Akoko, n’ijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, ṣebugbe ni wọn ko sọwọ awọn ajinigbe lasiko ti wọn n pada bọ lati ibi ti wọn ti lọọ taja ninu ọja Isua Akoko.
Awọn agbebọn ọhun la gbọ pe wọn dena de tọkọ-taya oniṣowo naa ninu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Avalon ti wọn wa, ti wọn si fipa wọ wọn wọnu igbo lọ.
Ni ibamu pẹlu alaye ti iyawo oloogbe ọhun ṣe fawọn oniroyin, o ni lilu lawọn ajinigbe naa lu ọkọ oun pa nibi ti wọn ti n fiya nla jẹ ẹ ki awọn eeyan awọn too ri owo itusilẹ awọn san fun wọn.
O ni lẹyin ti ọkọ oun ku tan lawọn oniṣẹẹbi naa kilọ foun pe oun ko gbọdọ lanu sọ ohunkohun fun awọn ti wọn jọ n dunaadura lori aago nipa iṣẹlẹ ọhun ti oun naa ko ba fẹẹ ku lojiji.
O ni wọn pada tu oun silẹ lẹyin ti owo tẹ wọn lọwọ tan, ṣugbọn ti oku ọkọ oun ṣi wa nikaawọ awọn agbebọn ọhun titi di asiko yii.
Ohun ta a gbọ ni pe awọn fijilante, ẹsọ Amọtẹkun atawọn ọlọpaa ti wa ninu igbo to wa lagbegbe naa lati bii ọjọ meji sẹyin lati ṣawari oku oloogbe ọhun lọnakọna, ṣugbọn akitiyan wọn naa ko ti i so eso rere ni gbogbo igba ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.
Eyi ki i ṣe igba akọkọ tawọn agbebọn yoo maa ṣọṣẹ loju ọna Iṣẹ si Isua, laipẹ yii ni wọn yinbọn pa ọlọpaa kan lagbegbe yii kan naa, ti wọn si gbe ibọn rẹ lọ lẹyin ti wọn pa a tan.