Gbenga Amos, Ogun
Beeyan ko ba ṣe nnkan etufu, onitọhun ko le maa kiyesi ẹyinkule, bi Usman Aliyu ṣe n wo fẹtofẹto bii ole aketi nigba to fẹẹ gun ọkada lọjọ kẹrinla, oṣu Kejila yii, ti wọn lo n gbọ jinnijinni bo ṣe n sọ fọlọkada naa pe ko gbe oun lati ilu Onigbẹdu lọ si ilu Papalanto, nijọba Ewekoro, ipinlẹ Ogun, lo mu kawọn aladuugbo fura si i, aṣe ọkan lara awọn ajinigbe ti wọn n paayan ninu igbo Onigbẹdu ni, ọwọ ti ba meji ninu wọn ṣaaju, lawọn yooku ba n wa ọna lati sa lọ, tọwọ fi ba a.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, lo sọrọ yii di mimọ f’Alaroye, ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila yii.
Oyeyẹmi ni latigba tawọn ọlọpaa lati ẹka ileeṣẹ wọn to wa l’Ewekoro, ti lọọ ka awọn ajinigbe ti wọn fi igbo agbegbe Onigbẹdu ṣe ibuba wọn, tọwọ si ba meji ninu wọn, ti wọn tu Oluwaṣeyi Ọlọrunṣogo to wa loko onde wọn silẹ, atigba naa lawọn yooku ti fọn ka sinu igbo naa, ti kaluku wọn n wa ọna ti yoo fi sa lọ.
Amọ awọn ọlọpaa, atawọn ẹṣọ Amọtẹkun, pẹlu awọn ọlọdẹ adugbo ibẹ ko jẹ kawọn eeyan rọna lọna, tọsan-toru ni wọn n dọdẹ wọn bi ologbo ṣe n dọdẹ ekute, gẹgẹ bii aṣẹ ti Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, pa.
Nigba tọwọ ba Aliyu, ti wọn wọ ọ de teṣan, o jẹwọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe ajinigbe loun loootọ. O ni mẹfa lawọn tawọn wa nidii iṣẹ laabi ọhun, ati pe o ti pẹ diẹ tawọn ti n jiiyan gbe, amọ awọn ṣẹṣẹ de sagbegbe Onigbẹdu ni.
Wọn bi i leere nipa awọn eeyan ti wọn ti ji gbe sẹyin, lo ba jẹwọ pe awọn lawọn ji Ọgbẹni Abiọdun Owolabi kan atọrẹ ẹ, Fakorede Kazeem, gbe lọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, l’Abule Kípẹ̀, ni Idi-Ori, l’Abẹokuta. O lawọn pa Fakorere soju ọna nigba tawọn n fipa mu wọn lọ tọkunrin naa ko si le rin daadaa, nigba to jẹ irin kanmọkanmọ lawọn n rin lọ ni gbogbo oru yẹn, tori ewu awọn agbofinro ti wọn le maa tọpasẹ awọn bọ.
O lawọn tun ji ọmọọdun mẹwaa kan, Esther Adekunle, atọmọọdun mẹẹẹdogun kan, Adebayọ Adekunle, gbe l’Opopona Ọlọmọwẹwẹ, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, to lọ lo lawọn ṣe iyẹn.
Lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa ọhun lo lawọn tun ji Abilekọ Famurewa gbe l’Abule Ijaye Ṣoyọọye, l’Abẹokuta, ẹnu ọna ile ẹ lo lawọn ti gan an lapa lọjọ naa, igba tọkọ ẹ, Festus Famurewa, si fẹẹ figbe ta, lawọn fibọn pade ẹnu to la ọhun, bo tilẹ jẹ pe awọn tu iyawo rẹ yii silẹ lẹyin ọjọ diẹ, nigba tawọn mọlẹbi ti san owo itusilẹ fawọn.
Aliyu ni ko tan sibẹ o, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, to kọja, Abule Olujọbi, to wa laarin ilu Itori si Onigbẹdu, lawọn ti ji eeyan meji kan gbe, Azeez Ọlatunji ati Moroof Ọṣọba, ṣugbọn awọn o ṣe wọn leṣe o, wọn kan wa lọdọ awọn fungba diẹ ni, igba tawọn mọlẹbi wọn si ti ko owo itusilẹ tawọn jọ fẹnu ko le lori wa, wọn tu wọn silẹ.
Awọn ọtẹlẹmuyẹ wa diẹ kan ninu awọn ti afurasi ọdaran yii jẹwọ p’awọn ji gbe lati fidi ọrọ to sọ mulẹ, awọn ẹni-ori-yọ naa si ti foju rinju pẹlu ẹ, wọn ni loootọ ni, ọkan lara awọn amookunṣika ti wọn fi awọn sahaamọ ninu igbo lọjọsi ni.
Kọmiṣanna ọlọpaa ti paṣẹ pe ki wọn tubọ dọdẹ awọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku, o ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ ma jafara lori iwadii to lọọrin nipa awọn tọwọ ba yii, o ni gbogbo wọn ni wọn maa kan dudu inu ẹkọ niwaju adajọ laipẹ.