Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn agbebọn to ji awọn akẹkọọ poli mẹrin gbe l’Akoko lọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kẹrinlelọgbọn, oṣu Kejila yii, ti kan sawọn ẹbi wọn, ti wọn si n beere fun miliọnu mẹta Naira lori ọkọọkan wọn.
Awọn akẹkọọ ọhun ti wọn jẹ ọmọ ile-ẹkọ Gbogbonṣe ti ipinlẹ Kogi, eyi to wa ni Lọkọja ati awakọ wọn ti wọn porukọ rẹ ni Mọmọdu lawọn agbebọn ọhun ji laarin Akunnu si Ajọwa Akoko, lasiko ti wọn n bọ nile fun ayẹyẹ ọdun Keresimesi.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe aigbọran Mọmọdu to jẹ awakọ mọto naa lo fi ko awọn ọmọ ọlọmọ sinu iyọnu.
Wọn ni wọn ti kọkọ kilọ fun awakọ naa ko ma ṣe gba ọna Ajọwa-Akunnu tawọn eeyan ti mọ bii ibuba ati ibudo awọn ajinigbe, wọn parọwa fun un ko lọọ gba ọna mi-in, iyẹn oju ọna Akùnnù, Ìkáràm ati Gèdègédé, eyi tawọn awakọ n gba bayii, bo tilẹ jẹ pe o jinna diẹ, ṣugbọn ti ọkunrin naa kọ jalẹ.
Igbakeji alaga ijoba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko tẹlẹ, Ọgbẹni Ajayi Bakare, ninu ọrọ to ba oniroyin kan to filu Akoko ṣebugbe, Alaaji Ibrahim Kilani, sọ lo ti ni obi awọn akẹkọọ ọhun tun bẹ Mọmọdu lori ọna to fẹẹ gba naa, ti wọn si ṣeleri lati fi kun owo ọkọ rẹ to ba gbe awọn ọmọ wọn gba ọna Ìkáràm ati Gèdègédé, ṣugbọn ti ko gbọran si wọn lẹnu.
O ni awọn agbebọn ọhun ti pe obi awọn akẹkọọ naa, ti wọn si ti ni wọn gbọdọ waa san miliọnu mẹta Naira lori ọkọọkan wọn ki wọn too tu wọn silẹ, miliọnu mẹrin Naira ni wọn n beere lọwọ ẹbi awakọ to gbe wọn gẹgẹ bii owo idande tirẹ.
Ọrọ awọn akẹkọọ tí wọn ṣẹṣẹ ji gbe naa ni wọn lo ti da omi tutu sọkan awọn eeyan Ajọwa Akoko atawọn ilu mi-in nibi tawọn akẹkọọ mẹrẹẹrin ti wa, adura ti wọn si n gba bayii ni ki wọn pada ri awọn ti wọn ji gbe ọhun layọ ati alaafia.