Bọlanle n bọ lati ṣọọṣi lọjọ Keresi, lọlọpaa ba yinbọn pa a niṣeju ọkọ ẹ l’Ajah

Faith Adebọla, Eko

 Ẹni pe ṣonṣo yoo ri ṣonṣo ni, ọlọpaa ASP kan ti wọn o ti i darukọ ẹ ti kọwe si ẹjọ ati wahala, ki i ṣe wahala lasan paapaa, ẹjọ apaayan lo kọwe si, o si ti ri ẹjọ ọhun, pẹlu ẹsun ti wọn fi kan an pe o yinbọn pa agbejọrọ kan, Bọlanle Raheem, lasiko tobinrin naa, ọkọ ẹ, awọn ọmọ ẹ mẹrin, pẹlu aburo ẹ kan n dari bọ lati ṣọọṣi ti wọn lọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Disẹmba yii.

Alaroye gbọ pe yanpọnyanrin nla ni iṣẹlẹ to waye labẹ biriiji Ajah, nibi tawọn ọkọ ti maa n lọri pada, da silẹ, latari bawọn araalu to wa nitosi tọrọ naa ṣeju wọn ṣe fara ya, wọn ni aribọnyọ ẹda kan ni ọlọpaa to fẹmi obinrin arẹwa naa ṣofo lai nidii.

Ohun ta a gbọ ni pe ni nnkan bii aago mọkanla owurọ lobinrin agbẹjọro yii wa ọkọ de abẹ biriiji naa, o fẹẹ ṣe ṣe yuu-tọọnu, lawọn ọlọpaa ba da a duro.

Awọn tọrọ naa ṣoju ẹ sọ pe ọkọ to wa niwaju ni Bọlanle n ro’wọ fun ko le raaye paaki, afi bi iro ibọn ṣe dun lau lojiji, to si ba obinrin naa nijooko dẹrẹba to wa, lọrọ ba di yanpọnyanrin.

Wọn sare du ẹmi oloogbe yii, wọn gbe e lọ sọsibitu aladaani kan to wa nitosi, ṣugbọn aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ, ọmọyẹ ti rinhooho wọja, Bọlanle ti dakẹ.

Wọn loju-ẹsẹ tọlọpaa yii ti ri ohun to ṣẹlẹ lo ti ba ẹsẹ ẹ sọrọ, amọ ero atawọn ọlọpaa ẹgbẹ ẹ ni wọn le e mu, ti gbogbo wọn si ko rẹi-rẹi lọ si tọlọpaa ni teṣan Ajah.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti mu agbofinro to tẹ ofin loju yii, awọn si ti bẹrẹ iwadii lọri ẹ.

Hundeyin ni: “Oni, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Disẹmba, wọn fẹsun kan ọlọpaa ASP kan pe o yinbọn pa obinrin kan l’Ajah. A ti mu ọlọpaa ASP naa, a ti sọ ọ sahaamọ, a si ti n gbe e lọ si ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ wa to wa ni Panti, lagbegbe Yaba, fun iwadii to lọọrin.

‘‘Bakan naa, Ọga agba patapata ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa, IGP Usman Alkali Baba, ti gbọ siṣẹlẹ yii, o si ti paṣẹ pe ki wọn ṣewadii to peye lori ẹ’’.

Ninu ọrọ kan ti Alukoro apapọ fawọn ọlọpaa, CSP Olumuyiwa Adejọbi, fi sori ikanni tuita rẹ lorukọ ọga rẹ, o ni Alkali Baba koro oju si iṣẹlẹ yii, tori iwa naa ko ba ofin ati ilana iṣẹ awọn ọlọpaa mu, o ni iwa to n ta ẹrẹ saṣọ aala ileeṣẹ ọlọpaa ni, tori ẹ, awọn maa tuṣu ọrọ naa desalẹ ikoko, ẹlẹṣẹ kan ko si ni i lọ laijiya.

Olori awọn ọlọpaa naa tun kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi oloogbe, awọn ọrẹ ati alajọṣiṣẹ, o si ṣadura pe k’Ọlọrun tẹ ẹ safẹfẹ rere.

Yooba bọ, wọn ni ẹni to gbe igi eleera sori, ogun jari-jarun lo kọwe si. Ẹgbẹ awọn lọọya, Nigeria Bar Association, ti dide sọrọ yii, wọn lawọn o ni i gba ki ọmọ ẹgbẹ awọn ku iku ika bẹẹ. Oloogbe Bọlanle Raheem, to jẹ ọmọ-ẹgbẹ NBA, ẹka ti Eko, lawọn agbẹjọro ẹgbẹ sọ pe lọọya to kọṣẹ mọṣẹ, to si n ṣojuṣe ninu rẹ ẹgbẹ ni.

Amofin agba Y C Maikyau, Aarẹ ẹgbẹ NBA ni awọn ti dide lori ọrọ naa, awọn si maa ba afurasi ọdaran ọhun ṣẹjọ lati gba idajọ ododo fun oloogbe atawọn mọlẹbi ẹ.

Leave a Reply