Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Pẹlu ibinu ni Gomina Rotimi Akeredolu fi sọko ọrọ lu Dokita Oluṣẹgun Mimiko lasiko ti wọn n fọro wa a lẹnu wo lori tẹlifisan aladaani kan laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ ta a wa yii.
Ninu ifọrọwerọ ti Arakunrin ṣe pẹlu atọkun eto naa lo ti juwe ọrẹ rẹ tẹlẹ ọhun bii ọdalẹ ati alairikan-ṣekan.
Akeredolu ni ofo ọjọ keji ọja lasan ni ajọṣepọ to wa laarin Mimiko ati Ajayi, eyi ti ko le tu irun kankan lara erongba oun lati wọle pada ninu eto idibo to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu to n bọ.
O ni bo tilẹ jẹ pe oun mọ pe iwa ọtẹ wa ninu ọkunrin ọmọ bibi ilu Ondo ọhun, sibẹ oun gbiyanju ati tẹ ẹ lọrun niwọn bi agbara oun ti mọ.
O ni bi Ajayi ko ṣe ri ibomi-in lọ lati dije ju ọdọ Mimiko lọ ti fihan pe iwa kan naa lo wa ninu awọn mejeeji.
Akeredolu ni gomina ana ọhun funra rẹ mọ pe oun ti lo asiko toun kọja ninu eto oṣelu ipinlẹ Ondo, o ni orukọ lasan lo n wa, ko si tun ba Ajayi na ninu owo rẹ.
Awọn ọrọ kobakungbe ti ko sẹni to gbọ iru rẹ ri lati ẹnu gomina ọhun lati bii ọdun mẹta ataabọ to ti wa lori aleefa lo n sọ
Koda nigba tawọn eeyan n pariwo pe o yẹ ki Akeredolu ṣe iwadii bi Mimiko ṣe nawo fun odidi ọdun mẹjọ to fi ṣakoso, esi to n fun wọn ni pe ko ṣeyii to kan oun lori a n wọ idi eniyan, o ni iṣẹ ilu toun fẹẹ ṣe loun fẹẹ gbaju mọ.
Gomina yii ko fi bo nigba naa pe ọrẹ imulẹ loun ati Mimiko, to si ni oun ko ni i gba ki ọrọ oṣelu lasan ba ibaṣepọ ogoji ọdun to ti wa laarin awọn jẹ.
Lati igba ti Ajayi ti darapọ mọ ẹgbẹ ZLP, ti Mimiko naa si tẹwọ gba a ni nnkan ti yipada, lẹyin igba naa lawọn eeyan ṣẹṣẹ n gbọ ti awọn ọrẹ mejeeji ọhun n sọ oko ọrọ sira wọn nita gbangba.