Oṣere tiata yii pariwo: Ẹ gba mi o, makẹta yii ti ba temi jẹ

Jọkẹ Amọri

Ohun to mu iyaale ile to fi n wa ẹkun mu bii gaari, ko ṣẹṣẹ nilo keeyan maa beere pe ki lo ṣe e, o yẹ ki tọhun ti mọ pe ọrọ naa le gidigidi ni.

Eyi ni ọpọ awọn ti wọn ri ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa to fi ilu Abẹokuta ṣe ibugbe nni, Abiọla Adekunle, to n sunkun kikan kikan ninu fido kan to gbe sori ikanni Instagraamu rẹ.

Ohun to fa a ti oṣere yii fi n sunkun, to si n mi amikan, ko sẹyin makẹta kan to ba a ta fiimu rẹ, ati eyi to ba oṣere agbalagba kan ti wọn n pe ni Iyaabeji Ọmọ araye le ṣe lati ọdun 2018, ti makẹta ti wọn porukọ rẹ ni Integrity Production yii si kọ ti ko sanwo fun oṣere naa.

Abiọla ni obinrin ti oun ba ṣe fiimu pẹlu ireti pe o maa ta, yoo rowo nidii rẹ ko rowo, nigba ti oṣere ẹgbẹ rẹ yii si bẹrẹ si i fa a kiri lo ni oun lọọ ya owo ele lati fi yanju gbese naa, eyi to si wa lọrun oun di baa a ṣe n sọ yii.

Ọmọbinrin naa ni ojoojumọ loun n bẹ makẹta yii ko sanwo naa, ṣugbọn ko dahun. O ni gbogbo igba ni makẹta yii si n gbe fiimu jade, ṣugbọn to kọ ti ko sanwo oun.

Oṣere yii ni o yẹ ki oun ti gbe fiimu mi-in jade lati ọjọ yii, ṣugbọn owo oun to ha si ọdọ makẹta yii ati gbese ti oun jẹ ko jẹ ki oun le ṣe eleyii.

O waa rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmo Naijiria pe ki wọn jọwọ, gba oun lọwọ makẹta yii, ki wọn ba oun bẹ ẹ ko sanwo oun foun.

Eyi ni bi oṣere naa ṣe ṣalaye ara rẹ.

‘‘Ẹ kaaarọ, ẹ kaalẹ nibi gbogbo ti ẹ ti n gbọ mi, ẹ jọwọ mo nilo iranlọwọ yin ni o. Ọrọ naa ti de pinpin ọkan mi patapata,mo ni lati jade sita sọrọ. Lọdun 2018, mo ba Iyaabeji ọmọ araye le pakeeji ere kan. Gbogbo awọn to ba mọ wọn, ọrẹ mọlẹbi mi ni wọn jẹ.

‘‘Emi naa si fẹẹ se fiimu kan ti mo pe ni ‘Oyẹku’. Nigba ti a ya ‘Oyẹku’ yẹn, a fọ tẹlifiṣan kan ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna igba Naira ataabọ (250,000). Gomina TAMPAN bayii, Owolabi Ajasa, le jẹrii si ohun ti mo n sọ yii. A ṣaa wa owo ni gbogbo ọna ti a fi ra tẹlifiṣan yẹn, ọwọ ọlọwọ ẹsẹ ẹlẹsẹ ni owo yẹn. Nigba ti Iyaabeji ọmọ araye le fẹẹ sẹ fiimu yẹn, wọn jẹ ko ye mi pe awọn lọọ ya owo ti awọn fi ṣe e yẹn ni. Mo ni ko si wahala, pe wọn maa ri owo wọn pada,  a ṣaa ṣe fiimu yẹn ‘Gain’ la pe taitu rẹ. Fẹmi Adebayọ, Ayọ Ọlaiya atawọn oṣere loriṣiiriṣii lo wa nibẹ. ‘Ọyẹku’ yẹn naa, mo ṣe e, lati 2018 ni mo ti ta fiimu yẹn fun makẹta, mi o rowo, iya yẹn bẹrẹ si i fa mi, nigba to ya mo lọọ ya owo, mo fi sanwo iya yii pada pẹlu owo ele. Mo wa n bẹ makẹta yẹn ko fun mi lowo iya yii pada. Ko pẹ ko jinna, wọn ni makẹta yii ni problẹẹmu, pe o ti kuro ni Naijiria. Gbogbo bi mo ṣe n gbiyanju lati ri wọn, niṣe ni wọn kan n yi mi kiri, lori owo mi, owo olowo.

‘‘Wọn n yi mi kaakiri, wọn ko fẹẹ sanwo yẹn pada titi di asiko yii. Wọn ti pada wa si ẹnu iṣẹ yii bayii o. Nnkan to n dun mi ni pe to ba jẹ pe owo wa lowọ mi ni, mi o ba ti ṣe fiimu mi-in, awọn to ba mi ni ẹnu iṣẹ yii atawọn to ju mi lọ nidii iṣẹ yii, gbogbo wọn ni wọn n gbe fiimu jade. Amọ nigba ti owo ti mo fi n ṣowo ti wa nita, owo Iyaabeji ọmọ araye le naa ti mo ya a ni, ti mo fi da a pada fun wọn, ẹni yẹn ṣi n sin mi ni owo yẹn pada, makẹta yii dẹ n gbe fiimu jade lojoojumọ, ko da owo mi pada fun mi, mo dẹ n bẹ ẹ, o ni gbogbo ohun ti mo ba fẹẹ ṣe, ki n lọọ ṣe e. Mo ni gbogbo ẹri lọwọ.

‘‘Ninu owo yii, miliọnu kan ni, wọn kọkọ fun mi ni ẹgbẹrun lọna aadọta Naira, ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ti wọn fun mi, ọdun to kọja ni wọn san an, o ku (950,000). Wọn tun san aadọta lọdun yii, nigba ti mo bẹrẹ si i yọ wọn lẹnu, wọn n bu mi, mi o sọrọ…

‘‘Mo ba makẹta yii sọrọ ko fun mi lowo mi, wọn ko fun mi,

Wọn si n gbe iṣẹ jade, wọn si n gbe owo fawọn eeyan. Ẹ jọwo, ẹ ba mi bẹ makẹta yii, Busayọ Odu lorukọ rẹ, ko san owo mi, kemi naa le ṣiṣẹ, mi o lẹnikan to n fun mi lowo. Bo jẹ ẹgbẹrun lọna ogun Naira lo fẹẹ maa san an, mi o kọ, ẹ ṣaa ba mi bẹ ẹ ko san owo mi fun mi’’.

Bẹẹ ni Bisọla pari ọrọ re.

Leave a Reply