Awọn Musulumi ilu Afọn ni ayẹyẹ ọdun Ọṣun ti wọn fẹẹ ṣe ko gbọdọ waye

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Igbimọ adari ẹṣin Musulumi niluu Afọn, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, ti jawe akiwọwọ fun arabinrin kan, Abimbọla Falilat, ti ọpọ eeyan mọ si Iya Ọṣun, pe ko saaye fun un lati ṣe ayẹyẹ ajọdun Ọṣun, eyi to fi si ọjọ karun-un, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023.

ALAROYE gbọ pe Arabinrin Abimbọla ti kede Tọsidee yii gẹgẹ bii ọjọ ti yoo ṣe ayẹyẹ ajọdun Ọṣun, ṣugbọn awọn igbimọ ẹlẹsin Musulumi niluu Afọn, ti sọ pe ala ti ko le ṣẹ ni, ko si tete yi ipinnu rẹ pada kiakia tori pe odi ẹwu ni Iya Ọṣun la bọrun

Ẹnikan to fi ọrọ naa to ALAROYE leti sọ pe idi ti wọn fi ni ayẹyẹ naa ko gbọdọ waye ni pe awọn eeyan to n bọ oriṣa Ọṣun ni wọn maa n ṣe ayẹyẹ ajọdun Ọṣun lọdọọdun, ṣugbọn ẹṣin Islaamu ni wọn n si niluu Afọn lati ayebaye, fun idi eyi, ko ma gbe ẹsin ibọriṣa wọ ilu naa. Wọn ni to ba fẹẹ ṣọdun Ọṣun, ko gba ilu Ọṣun lọ, nipinlẹ Ọṣun, tori pe ayẹyẹ naa ta ko ẹṣin Islaamu patapata.

Ko ti i ṣeni to mọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si, nitori ohun ti awọn kan to sun mọ Iya Ọṣun n sọ ni pe onikaluku lo ni anfaani lati sin ẹsin to ba wu u labẹ ofin ilẹ wa, ti ẹnikẹni ko si gbọdọ halẹ mọ ọn gẹgẹ bi awọn Musulumi ilu Afọn ṣe n ṣe yii.

Leave a Reply