Monisọla Saka
Hassan Adamu Shekarau, to ti figba kan jẹ aṣofin to n ṣoju ẹkun Birnin Gwari/Giwa, nileegbimọ aṣofin agba ilu Abuja, ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu to wa lori aleefa, APC, silẹ bayii, lai wo pe eto idibo gbogboogbo ọdun 2023 ti sun mọle.
Ninu lẹta to kọ lọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 yii, niluu Abuja, ni Sẹnetọ lati ipinlẹ Kaduna nigba kan ri ọhun ti ṣalaye awọn idi to fi gbe igbesẹ to gbe.
O fẹmi imoore han sawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, agaga awọn tipinlẹ Kaduna, ti wọn ti ṣe atilẹyin ọlọkan-o-jọkan fun un latẹyin wa. Ko sẹni to ti i le fidi ẹ mulẹ boya yoo lọọ dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP tabi ẹgbẹ mi-in ni.
Apa kan lẹta to kọ ka bayii pe, “Eyi ni lati fi erongba mi to yin leti, nipa ẹgbẹ oṣelu APC ti mo fẹẹ fi silẹ, eyi ti yoo bẹrẹ lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023”.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii kan naa, ni igbakeji akọwe to wa fun ṣiṣe kokaari awọn eeyan fun ipolongo ibo aarẹ fun Aṣiwaju Bọa Tinubu ni Aarin Gbungbun Ariwa, Ahmed Ibeto naa kọwe fipo silẹ. Ohun to sọ pe o fa a ni aisi iṣọkan laarin awọn ọmọ ẹgbẹ, eyi to ni o n fa kọnu-n-kọhọ laarin wọn ni gbogbo igba.
Bakan naa ni adari to wa fun ṣiṣe kokaari awọn ọdọ ni Ila Oorun-Ariwa fun ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ APC, Zanna Alli kọwe fipo silẹ. Lara idi ti ọkunrin naa loun fi fipo silẹ ni bi ẹgbẹ wọn ko ṣe fa ẹni to kun oju oṣuwọn, to si ni orukọ rere kalẹ fun awọn ọmọ Naijiria lati dije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn.