Ipokia ni Daniẹl at’ọrẹ ẹ ti lọọ ji ọkada gbe, ni wọn ba ko sọwọ So-Safe

Faith Adebọla

Daniel ti wọn sọ siho kiniun ninu Bibeli lawọn eeyan ti n gbọ, amọ ti ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn ti wọn n pe ni Daniel Adeyanju yii, ahamọ awọn ọlọpaa ni wọn sọ oun si ni tiẹ, iwa ibi ọwọ ẹ lo si gbe e debẹ, ọkada Bajaj ẹni ẹlẹni kan lo lọọ ji gbe, oun ati afurasi ẹlẹgbẹ ẹ, Emmadu Matthew, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn.

Alukoro awọn ẹṣọ alaabo So-Safe nipinlẹ Ogun, Moruff Yusuf, sọ f’Alaroye pe ile Baba Uwuku, to wa laduugbo Oko Cashew, ni ilu Ihunbọ, nijọba ibilẹ Ipokia, ni Daniẹl n gbe, nigba ti Matthew n gbe Izini, laduugbo Iponle, Isakete, lorileede Olominira Bẹnẹ, to paala pẹlu Naijiria lagbegbe ọhun.

Wọn ni lọjọ kẹrin, oṣu Ki-in-ni, ọdun yii, ni awọn ẹṣọ So-Safe, eyi ti ọga wọn kan, Abdulkareem Abdulrazaq, ko sodi, n ṣe patiroolu kiri igboro pẹlu ọkọ wọn. Asiko naa ni wọn ṣakiyesi awọn gende meji ti wọn n ṣe aayan pẹlu oku ọkada kan lẹgbẹẹ igbo, ọkada naa taku, wọn o si ri ojuutu ẹ.

Awọn So-Safe pe wọn lati beere boya awọn ni wọn ni ọkada naa, wọn lawọn lawọn ni in, ni wọn ba beere pe iwe ẹ da, amọ dipo ki wọn kowee jade, niṣe ni wọn bẹ lugbẹ, ti wọn n sa lọ, eyi to mu kawọn So-Safe fura pe afaimọ ni ki i ṣe ẹru ole ni wọn pe ni tiwọn yii.

Ṣa, wọn gba, wọn fi ya wọn, wọn si ri awọn mejeeji mu. Lasiko iwadii lawọn afurasi adigunjale yii jẹwọ pe awọn ji ọkada Bajaj naa ni, wọn ni Ita-Ẹgbẹ lawọn ti ji i.

Ayẹwo fihan pe Ọgbẹni Wasiu Akanni lo ni ọkada ti nọmba rẹ jẹ TRE742UX ọhun. Wọn ni niṣe lọkunrin naa gun ọkada yii waa ṣọdun nile, o si paaki rẹ sẹgbẹẹ agboole wọn ni Ita-Ẹgbẹ, lalẹ aisun ọdun tuntun, iyẹn ọjọ Satide, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun to lọ, ṣugbọn ki wọn too pariwo hapi niu yia, ọkada naa ti dawati, Daniel ati Matthew ti palẹ ẹ mọ, wọn ji i gbe.

Ṣa, wọn ti fa awọn afurasi mejeeji le awọn ọlọpaa lọwọ, lẹka ileeṣẹ wọn to wa n’Idiroko, nipinlẹ Ogun, fun iwadii to lọọrin.

Wọn lawọn ati ọkada ti wọn ji ọhun yoo foju bale-ẹjọ ti iwadii ba ti pari laipẹ.

Leave a Reply