Idowu Akinrẹmi, Ikire
Iwadii ti bẹrẹ lati mọ awọn ẹni ibi to ṣeku pa akẹkọọ ileewe Poli Iree, nipinlẹ Ọṣun, Ewebiyi Festus Adedoyin, to jẹ akẹkọọ nipa Okoowo (Business Administration) ati idi ti wọn ṣe pa a gan-an.
Ile ọmọkunrin naa to wa ni Popoola, niluu Iree, ni wọn pa a si, lẹyin ọjọ kẹrin ni awọn ti wọn jọ n gbele si too ri oku akẹkọọ naa ninu yara rẹ, to ti wu gelete.
Ẹnikan to fiṣẹlẹ naa to wa leti, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ ẹ ṣalaye pe oun fura pe oorun abaadi kan n fẹ wa lati inu yara ti Festus n gbe, to si jẹ pe o ti to bii ọjọ mẹrin ti awọn ti ri i gbẹyin, eyi lo si fa a tawọn fi fagidi ja ilẹkun ile ọhun lati mọ ohun to n run jade lati inu ile naa.
Iyalẹnu lo jẹ pe oku Festus ni wọn ba ninu agbara ẹjẹ ninu yara yii.
Ọkunrin yii ni o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn kan ni wọn ṣeku pa akẹkọọ ọhun, pẹlu bo ṣe je pe bii ọna mẹta ni wọn ti gun un lọbe yika ara rẹ. Ṣugbọn lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ko ti i ṣeni to le fidi iku to pa akẹkọọ naa mulẹ tabi awọn to pa a, ati idi ti wọn fi pa a
ALAROYE gbọ pe nitori ileewe to ṣee ṣe ko wọle laipẹ yii ni ọmọkunrin naa ko fi lọ sile.
Awọn ẹbi Festus ti gbe oku ọmọ wọn lọ, bẹẹ ni awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ aburu naa.