Eto idibo le ma waye ti… –INEC

Faith Adebọla

Aayan fẹẹ jo, amọ o n bẹru adiẹ to ṣi wa lode. Ọrọ yii lo ṣe wẹku pẹlu ikilọ ti Alaga ajọ eleto idibo apapọ ilẹ wa, Independent National Electoral Commission, INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ṣe lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kin-in-ni yii, pe o wu ajọ naa lati ṣeto idibo to mọyan lori, to si ṣetẹwọgba lọdun yii, amọ ti idunkooko mọ ni, idaluru, biba dukia jẹ, ifẹmiṣofo ati eto aabo to mẹhẹ yii o ba rọlẹ daadaa tabi ko dopin, afaimọ lawọn o ni i sun eto idibo gbogbogboo ti gbogbo eeyan n foju sọna fun naa siwaju, tabi kawọn tiẹ wọgi le e patapata, tori ewu ṣi n bẹ loko Longẹ bayii.

Nibi apero ati idalẹkọọ kan to da lori ipese eto aabo lasiko idibo, eyi ti wọn ṣe niluu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, ni Yakubu ti sọrọ ọhun.

Ọgbẹni Abdullahi Zuru, Alaga igbimọ to n ri si eto idanilẹkọọ lori ọrọ idibo, to ṣoju fun Mahmood Yakubu, nipade ọhun, sọ pe “ti eto aabo to polukurumuṣu lorileede yii ko ba sunwọn si i, ti wọn o ba dẹrọ ẹ tabi ki wọn tiẹ kasẹ ẹ nilẹ patapata, o le mu ka wọgi le esi idibo kan tabi ka sun eto idibo siwaju lawọn ẹkun idibo kan, eyi si le mu ko ṣoro lati kede esi idibo, bi iru ẹ ba si ṣẹlẹ, ipenija nla le de ba ofin ilẹ wa.”

Amọ, Yakubu ni ni ti ajọ INEC tipatipa ni ṣokoto fi i wọdi oku lọrọ ipese aabo jẹ, o ni gbogbo ohun to ba gba lawọn maa fun un lati pese aabo to peye fawọn oṣiṣẹ, awọn dukia, ẹrọ, ati lilọ-bibọ eto idibo naa, bo tilẹ jẹ pe ibi tagbara awọn ba gbe e de lawọn maa duro si, tori ibi tọwọ ba gun de lapa maa gun mọ.

O ni: “A o koyan eto aabo to muna doko lasiko idibo kere rara, a mọ pe o ṣe pataki ki ayika to tura, to fọkan balẹ, to si rọju wa lati ṣeto idibo ti ko ni kọnu-n-kọhọ ninu, to wa deede, to ṣee gbiyele, to si pari sibi to daa, iru eto idibo bẹẹ maa ṣaleekun agbara ijọba awa-ara-wa ni.

“Tori bẹẹ, ba a ṣe n gbaradi fun eto idibo gbogbogboo lọdun 2023, ajọ INEC ko ni i kẹrẹ lati ri i daju pe eto aabo to lọọrin, to duro digbi, wa fun awọn oṣiṣẹ rẹ, ati gbogbo nnkan eelo idibo naa.

“Nnkan to tubọ mu ki eyi ṣe koko ni pe ọrọ to hande ni ipenija eto aabo lorileede yii, ati pe ọpọ awọn oṣiṣẹ wa lasiko idibo naa maa jẹ awọn agunbanirọ, awọn ọdọ ti wọn maa wa lawọn ibudo eto idibo kaakiri, ọpọ wọn si ni wọn ti koju wahala titi doju iku latẹyinwa.

“A o fẹ kiru ẹ ṣẹlẹ mọ, ko si gbọdọ ṣẹlẹ.

“Nitori naa, awọn ẹṣọ alaabo ni pataki, atawọn oṣiṣẹ eleto idibo, gbọdọ wa lojufo daadaa, ki wọn si maa ṣọ gbogbo nnkan to n lọ layiika wọn, tori toju tiyẹ laparo fi n riran, a si ni lati pese irinṣẹ ti wọn maa lo tọrọ pajawiri ba ṣẹlẹ fun wọn,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ni INEC kede pe eto idibo sipo aarẹ, tawọn aṣọfin agba, iyẹn awọn sẹnetọ, ati tawọn aṣoju-ṣofin apapọ yoo waye kaakiri origun mẹrẹẹrin orileede yii.
Ọsẹ meji lẹyin naa ni idibo tawọn gomina atawọn aṣofin ipinlẹ yoo tẹ le e.

Leave a Reply