Faith Adebọla
Bijọba ni yoo wa a o, bawọn mọlẹbi wọn si ni, bo si jẹ wọn maa wa ọgbọn mi-in da ni, iyowu ko jẹ, miliọnu lọna ọgọrun-un mẹfa Naira ati ogun, (N620m) lawọn ajinigbe ti wọn ji awọn ero to fẹẹ wọkọ reluwee ni Igueben, ipinlẹ Edo, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni o gbọdọ tẹ awọn lọwọ, kawọn ka a ko pe perepere, kawọn too tu eeyan mọkanlelọgbọn to wa lahaamọ awọn silẹ.
Alakooso ẹgbẹ awọn ọdọ ẹya Esan to n pe fun iṣejọba rere ati idajọ ododo, nipinlẹ Edo, iyẹn Esan Youth for Good Governance and Social Justice, Ọgbẹni Benson Odia, lo kẹ ọrọ yii sawọn oniroyin leti lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu yii.
O ni gẹgẹ bii iṣe wọn, awọn ajinigbe naa ti n pe lara awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe, wọn si ti n ba wọn sọrọ lori bi wọn ṣe maa tu awọn ti wọn mu londe lakata wọn silẹ.
O lawọn ajinigbe naa ni ori-o-jori ni owo itusilẹ tawọn maa gba, miliọnu lọna ogun, tuẹnti miliọnu Naira lawọn maa gba fun ọkọọkan awọn ti wọn ko wọgbo ọhun.
O lawọn ajinigbe naa sọ pe kẹnikẹni ma fakoko awọn ṣofo lori idunaa-dura owo itusilẹ ọhun o, tori awọn o ni i din-in, miliọnu ogun Naira fẹni kọọkan naa ko gbọdọ ja leti rara.
Odia ni ohun tawọn afurasi ọdaran yii n beere yii yaa-yan lẹnu, ko si dun-un-gbọ seti, o waa rọ ijọba atawọn oṣiṣẹ eleto aabo, paapaa awọn ṣọja, atawọn ọlọpaa, lati tẹpẹlẹ mọ bi wọn ṣe maa ri awọn ti wọn ji gbe naa gba pada lai sewu.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, Ọgbẹni Chidi Nwabuzor, loun o ti i le fidi ọrọ yii mulẹ, amọ oun naa ti gbọ pe awọn ajinigbe naa n beere owo gọbọi gẹgẹ bii owo itusilẹ.
Amọ ṣa o, Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Edo, Chris Nehikhare, sọ laṣalẹ ọjọ Aje pe eeyan mejilelọgbọn lawọn ajinigbe naa ji gbe nibudokọ reluwee ọhun. O lawọn ti ri mẹfa lara wọn gba pada, akitiyan si n tẹsiwaju lati doola ẹmi awọn yooku.
Tẹ o ba gbagbe, ko ti i ju oṣu mẹrin sẹyin ti awọn to ṣẹku sakata awọn ajinigbe ti wọn kọ lu reluwee lọna Abuja si Kaduna, ninu oṣu Kẹta, ọdun to kọja, gba itusilẹ lẹyin tawọn mọlẹbi wọn ti sanwo gọbọi fun wọn, lawọn agbebọn tun rẹbuu ọkọ reluwee ilẹ wa mi-in lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu Ki-in-ni, ta a wa yii, wọn ṣe ọpọ eeyan leṣe, wọn si ji ọpọ ero gbe lọ.
Irọlẹ ọjọ Satide niṣẹlẹ yii waye ni ibudokọ reluwee Tom Ikimi to wa ni Igueben, nijọba ibilẹ Igueben, nipinlẹ Edo. Ọpọ ero to duro lati wọ reluwee to n lọ lati Igueben si ilu Warri ni wọn fara kaaṣa akọlu ọhun. Alaroye gbọ pe maneja teṣan naa, Ọgbẹni Godwin Okpe, ati olori ẹṣọ alaabo teṣan ọhun wa lara awọn ti wọn ji gbe naa.