Eyi ni bi ori ṣe ko ọga agba ile-ẹkọ imọ-ẹrọ Ẹsa-Oke yọ lọwọ awọn agbanipa 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ori lo ko Dokita Samson Adegoke to jẹ ọga agba ile-ẹkọ imọ-ẹrọ to wa niluu Ẹsa-Oke, nipinlẹ Ọṣun, yọ nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lọwọ awọn agbanipa ti wọn fẹẹ gbẹmi ẹ.

ALAROYE gbọ pe aago mẹrin irọlẹ ku diẹ ni ọga agba yii kuro ninu ọgba ile-ẹkọ ọhun, ko si ti i rin pupọ ti mọto Toyota Camry kan fi bẹrẹ si i le e, ti awọn to wa ninu rẹ si ṣina ibọn fun mọto Adegoke.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Dokita Adegoke ni Orita Eti-Ọọni to wa laarin Ẹsa-Oke ati Ijẹbu-Jẹsa ti mọto awọn agbanipa naa fi sare kọja siwaju, ti wọn si fẹẹ dabuu mọto oun.

O ni ohun ti Ọlọrun fi yọ oun ni pe tirela kan n bọ lọọọkan, ko si faaye gba awọn ẹniibi naa lati kọja siwaju oun, o ni ibinu yẹn ni wọn fi ṣina ibọn bo mọto oun lati ẹgbẹ, ṣugbọn dẹrẹba oun ko duro rara.

Adegoke fi kun ọrọ rẹ pe dẹrẹba oun n sare lọ titi ti mọto naa ko fi le rin mọ, ṣugbọn ko si ẹni to fara pa laarin oun ati dẹrẹba oun.

O loun ti fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa ilu Ijẹbu-Jẹsa leti, wọn si ti ṣeleri lati gbe igbesẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe awọn ti gbọ nịpa iṣẹlẹ naa, iwadii si ti bẹrẹ lori rẹ.

Leave a Reply