Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Igbimọ to n gbọ ẹsun to ṣuyọ ninu idibi gomina to waye nipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, ti dajọ pe Alhaji Gboyega Oyetọla li jawe olubori ninu ibo naa
Ninu idajọ naa, to bẹrẹ laago mẹsan-an aarọ kọja iṣẹju mẹrinlelọgbọn, ni Onidaajọ Kume to jẹ alaga igbimọ ọhun ti sọ pe leyin ti awọn yọ adiju ibo, Oyetọla ni ibo 314, 921 nigba ti Adeleke ni ibo 290,266.
Bo tilẹ jẹ pe ọkan lara awọn onidaajọ mẹtẹẹta naa sọ pe oun ko fara mọ idajọ naa, sibẹ ile-ẹjọ sọ pe Oyetọla lo wọle ibo naa.
Ọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022, ni gomina tẹlẹ, Adegboyega Oyetọla ati ẹgbẹ APC gbe Gomina Ademọla Adeleke, ẹgbẹ PDP ati ajọ INEC lọ sile ẹjọ lori esi idibo naa.
Dokita Abiọdun Layọnu (SAN) lo ṣoju fun awọn olupẹjọ, Ọjọgbọn Paul Ananaba lo ṣoju olujẹjọ kin-in-ni, Dokita Niyi Owolade ṣoju olujẹjọ keji, nigba ti Nathaniel Ọkẹ ṣoju fun olujẹjọ kẹta.
Lara awọn ẹsun ti Oyetọla ati ẹgbẹ APC gbe lọ si kootu ni pe Gomina Adeleke ko ni ojulowo iwe-ẹri lati fi dupo gomina ninu idibo naa.
Bakan naa lo ni adiju ibo wa lawọn ibudo idibo to din diẹ ni ẹgbẹrin kaakiri ijọba ibilẹ mẹwaa nipinlẹ Ọṣun eyi to si tako agbekalẹ ofin eto idibo orileede yii.
Awon ijọba ibilẹ ti Oyetọla gbe esi idibo wọn lọ si kootu ni Ariwa Ẹdẹ, Guusu Ẹdẹ, Ẹgbẹdọrẹ, Ejigbo, Ila, Iwọ-Oorun Ileṣa, Irẹpọdun, Obokun, Ọlọrunda ati Oṣogbo.
Ninu atupalẹ idajọ rẹ, Kume, ṣalaye pe olupẹjọ kuna lati pe ẹlẹrii lori ẹsun pe ayederu iwe ẹri ni Adeleke lo lati fi dupo, o ni o yẹ ki wọn ranṣẹ pe ọga agba ileewe to fun Adeleke ni iwe ẹri lorukọ ipinlẹ lasiko ti ko ti i si ipinlẹ to n jẹ Ọṣun.
O ni niwọn igba ti Adeleke ti waa fi awọn iwe-ẹri miiran silẹ yatọ si ti ileewe girama to lọ niluu Ẹdẹ to n da ariyanjiyan silẹ, o kunju osunwọn lati dupo.
Lori adiju ibo, Kume ṣalaye pe awọn agbẹjọro olupẹjọ ti fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni adiju ibo wa lawọn ijọba ibilẹ mẹfa.
Ẹsẹ ko gbero nile-ẹjọ giga to wa niluu Osogbo, nipinlẹ Ọṣun, nibi ti idajọ lori ẹjọ naa ti waye.
Fọfọọfọ ni awọn ọlọpaa, ọtẹlẹmuyẹ, awọn sifu difẹnsi atawọn ẹṣọ aabo loriṣiiriṣii kun ọgba kootu naa.
Lati ẹnu ọna abawọle ni awọn agbofinro ti n yẹ ara awọn to fẹẹ wọnu kootu naa wo lati ri i pe wọn ko wọnu ọgba kootu yii pẹlu awọn ohun to lodi sofin.
Bẹẹ ni awọn ọlọpaa wa kaakiri awọn agbegbe kọkọkan niluu Oṣogbo ti wọn mọ pe o ṣee ṣe ki wahala bẹ silẹ lẹyin idajọ naa.