Lasiko ti Tọpẹ n ko ẹrun to ji ni ṣọọṣi Kerubu jade lo ko sọwọ ẹṣọ Amọtẹkun l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni tolohun. Ọrọ yii lo ṣe rẹgi pẹlu ọmọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogoji kan, Temitọpẹ Ọlọjẹde, to jẹ pe o pe to ti maa n jale ninu awọn ile-ijọsin to wa lagbegbe Ogo-Oluwa, niluu Oṣogbo, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ laipẹ yii.

Alaamojuto ẹṣọ Amọtẹkun niluu Oṣogbo, Ajagun-fẹyinti Bashir Adewimbi, ṣalaye pe ni Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, ni ọwọ tẹ Temitọpẹ lasiko to fẹẹ jale ninu ṣọọṣi Kerubu naa.

O ni awọn ti wọn wa lagbegbe ṣọọṣi Kerubu ati Serafu ọhun ni wọn kẹẹfin pe ẹnikan ti wọnu ibẹ lati ṣiṣẹ ibi, kia ni wọn si pe awọn Amọtẹkun lori foonu.

Lasiko ti afurasi yii n wa ọna lati ko awọn nnkan to ji bii ilu, aago atawọn nnkan mi-in jade lo ko si awọn awọn ẹṣọ Amọtẹkun, ti wọn si gbe e lọ si ọfiisi wọn.

Adewimbi fi kun ọrọ rẹ pe ninu ifọwọwerọ lọkunrin yii ti jẹwọ pe ki i ṣe igba akọkọ niyi ti oun yoo ja awọn ṣọọsi to wa lagbegbe naa lole.

Ni bayii, wọn ti fa a le awọn ọlọpaa lọwọ lati tẹsiwaju ninu iwadii, lẹyin eyi ni ireti wa pe yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply