Bi Tinubu ba wọle sipo aarẹ pẹnrẹn, Yoruba n lọ soko-ẹru ẹleekeji ni – Okunrounmu

Faith Adebọla

“Tinubu ti di wahala sọrun ọpọ eeyan. Ko nifẹẹ otitọ fawọn eeyan ilẹ Yoruba. Ta a ba dibo fun un, oko-ẹru ẹlẹẹkeji ni Yoruba n lọ yẹn. Ẹ o ri gbogbo ọgbọnkọgbọn ẹ lati pin ẹgbẹ Afẹnifẹre niya ni.

“Tinubu ni ko jẹ ki Amọtẹkun wa nipinlẹ Eko bii tawọn ipinlẹ Yoruba yooku. Oun naa lo ti Naijiria wọnu ajaga ta a ba ara wa yii. Oun lo gbe Buhari le wa lori nigba yẹn. Buhari ti Tinubu ṣatilẹyin fun naa lo le ijọba awa-ara-wa danu, to le awọn oloṣelu danu lọdun 1984, to fibọn gbajọba, to si foju awọn oloṣelu ilẹ Yooba ri mabo, titi kan Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ ti wọn sọ sẹwọn.”

Awọn ọrọ to n ja bọ bii oko yii lo jade lẹnu agba ẹgbẹ Afẹnifẹre to ti figba kan jẹ aṣofin agba nilẹ wa, Sẹnetọ Dokita Fẹmi Okurounmu, lasiko to n kopa ninu eto ifọrọwerọ ori ẹrọ ayelujara kan eyi ti ileeṣẹ redio Oodua ṣagbatẹru ẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji yii.

Okurounmu ni ẹtan ati imuni-lọbọ ni gbogbo eto ipolongo ibo to n lọ lode yii, tori bii igba ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ati oludije funpo aarẹ rẹ, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, n dọgbọn da aṣọ bo awọn araalu loju ni, o larun oju ni, ki i ṣe timu, ohun to han si gbogbo onilaakaye ọmọ Naijira ni pe asiko iṣejọba APC fọdun mẹjọ ti sọ Yoruba dero ẹyin, ipọnju ati oṣi lo mu wa, titi tijọba naa si fi n kogba sile yii, kaka kewe agbọn dẹ, ko ko lo n le si.

Okurounmu ni: “Ni ti Bọla Tinubu yii, nigba tawọn Fulani darandaran agbebọn n pa awọn eeyan wa ninu oko wọn, kaakiri abule wọn, Tinubu ko gbin pinkin, ko si sọ ọrọ ẹyọ kan bayii si i. Nigba ti iwọde ENDSARS di wahala ni too-geeti Lẹkki, tawọn ṣọja pa awọn ọdọ wa nipa ika, Tinubu ko sọrọ kan ṣoṣo nipa ẹ. Nigba ti eto aabo n bajẹ si i nilẹ Yoruba, ti wọn n pa awọn eeyan, ti Sunday Igboho dide lati gbeja awọn eeyan ẹ, njẹ ẹ gbọ ọrọ kan lẹnu Tinubu, wiwo lẹnu awo n wo ni.

Baba agbalagba naa ni lero toun, Ọgbẹni Peter Obi, ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party yoo ṣe Yoruba loore, tori idide ati okiki oludije naa lasiko ki i ṣe oju lasan, o lọwọ Ọlọrun Ọba ninu. O loun gbagbọ pe Obi yoo gbe Naijiria de ibi giga.

O ni: “Wọn ti sun awọn eeyan wa kangiri, afi kawọn eeyan fi ọwọ ara wọn gbara wọn kalẹ. Nnkan ti bajẹ lorileede yii debi pe afọju gan-an ri i pe ki i ṣe orileede ti gbogbo wa reti lati gbe la wa yii. Asiko awọn ọdọ la wa yii, awọn ọdọ lo ni ọjọ-ọla wa.”

Leave a Reply