Ajalu nla niṣẹlẹ naa jẹ fun idile Ọgbẹni Ayọ Ọladapọ, oṣere tiata ilẹ wa ti gbogbo awọn eeyan mọ si Ayọ Wolewole, ṣe ni ọkan lara awọn ọmọ rẹ ṣubu nibi to ti n gba bọọlu, to si gbabẹ jade laye.
Damilọla la gbọ pe o fẹran ere-bọọlu lati kekere, gbogbo awọn eeyan ni wọn si mọ ọn bii ẹni mọ owo, nitori o jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu kilọọbu kan ni Ido-Ọṣun, nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ, nipinlẹ Ọṣun.
O lọọ ṣoju kilọọbu rẹ nibi idije kan lọjọ Mọnde ọsẹ yii niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ. Wọn ti gba abala kin-in-ni, wọn si sinmi diẹ, ko pẹ pupọ ti wọn bẹrẹ abala keji ni Damilọla ṣubu lulẹ, ti ko si le dide mọ.
Awọn alakooso wọn gbe e digbadigba lọ sileewosan aladaani kan niluu naa, ṣugbọn bi awọn yẹn ṣe yẹ ẹ wo ni wọn ti sọ fun wọn pe ileewosan LAUTECH, niluu Oṣogbo, ni ki wọn maa sare gbe e lọ.
Nigba ti wọn yoo fi debẹ, ẹpa ko boro mọ, ẹnu ọna lawọn dokita ti sọ fun wọn pe ọmọ naa ti ku.
Ọjọ lṣẹgun, Tusidee, la gbọ pe wọn sinku Damilọla niluu Ido-Ọṣun, ti awọn oṣere tiata si n ba baba rẹ kẹdun iṣẹlẹ laabi naa titi di ba a ṣe n sọ yii.
Baba Damilọla lo ti figba kan jẹ gomina ẹgbẹ TAMPAN nipinlẹ Ọṣun, ko too di pe wọn yan an gẹgẹ bii igbakeji akọwe apapọ ẹgbẹ naa lorileede yii