Tori ọrọ to sọ, Fani-Kayọde ko si wahala tuntun

Faith Adebọla

Asiko yii ki i ṣe eyi to rọgbọ fun minisita feto igbokegbodo ọkọ ofurufu tẹlẹri nilẹ wa, to tun jẹ ọkan ninu awọn oludari igbimọ ipolongo ibo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde. Bo tilẹ jẹ pe o ti tọrọ aforiji fun bo ṣe fẹnu kọ lọsẹ to kọja, nibi to ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), pe wọn n ṣepade bonkẹlẹ kan pẹlu awọn lọgaa-lọgaa ileeṣẹ ologun ilẹ wa lati doju ijọba to wa lode yii de, kawọn ṣọja si gbajọba, eyi to mu kawọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ apapọ, Department of State Service (DSS), ranṣẹ si i ti wọn si fibeere po o nifun pọ lọsẹ to lọ ọhun, ọrọ naa ko ti i tan nilẹ o, nitori wọn ti tun ni ko maa yọju sawọn lojoojumọ bayii, yatọ si ẹẹkan lọsẹ ti wọn ti kọkọ paṣẹ fun un.

Ninu ọrọ kan ti ọkunrin tẹnu ẹ mu bii abẹfẹlẹ naa gbe sori ikanni abẹyẹfo rẹ, iyẹn tuita lopin ọsẹ yii, Fani-Kayọde kọ ọ sibẹ pe:

“Mo lọọ fi ara mi han lọfiisi awọn DSS lọjọ Wẹsidee, gẹgẹ bii adehun ti mo ni pẹlu wọn, ọpọ wakati si ni wọn fi da mi jokoo, ti wọn n bi leere ọkan-o-jọkan ibeere.

“O ti su mi, o si n tanni-lokun. Ṣugbọn o ya mi lẹnu bi wọn tun ṣe sọ pe ojoojumọ ni mo gbọdọ maa yọju sawọn bayii. Ma a ṣe ohun ti wọn wi.

“Ẹru o ba mi o. Ọlọrun wa lẹyin wa. Ọlọrun alagbara ati ologun ni. Ta lo le di i lọna?”

Bayii ni Fani-Kayọde sọ.

Tẹ o ba gbagbe, lọsẹ to kọja, lẹyin to kuro lakata awọn DSS lo ti tuuba lori ọrọ ifura nipa iditẹ-gbajọba to sọ, o loun ṣe misiteeki ni, o loun kabaamọ lori ọrọ naa, ati pe o yẹ koun kọkọ ṣewadii koun too bọ sori afẹfẹ, o loun tọrọ aforiji lọwọ ileeṣẹ ologun ati gbogbo awọn tọrọ naa le kọ lominu tabi ṣakoba fun.

Amọ, agbẹnusọ fun Alaaji Atiku Abubakar, to jẹ oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Ọgbẹni Phrank Shaibu, ti ni ki i ṣe pe ki Fani-Kayọde sọ pe oun kabaamọ nikan ni, o lo tun gbọdọ tọrọ aforiji lọwọ Atiku, ko si si jẹ kaye mọ pe oun ti ko ọrọ toun sọ naa jẹ.

Leave a Reply