Lẹyin ọpọ wakati tawọn mọlẹbi oloogbe ti n wa a, ti wọn o kofiri ẹ nibi kan, ti wọn o si ri ọkada, wọn kọri si teṣan ọlọpaa lẹka ileeṣẹ wọn to wa ni Ọbalende, n’Ijẹbu-Ode, lati fọrọ naa to wọn leti.
Ko pẹ lẹyin igba naa lolobo ta wọn pe wọn ri oku ọkunrin kan leti omi lagbegbe Agoro, oju-ẹsẹ si ni DPO teṣan ọhun ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ pe ki wọn lọọ wadii ohun to ṣẹlẹ, wọn si ba oku naa nibẹ loootọ, oku Amos Chukwuka ni, wọn ri gbogbo apa bi wọn ṣe ṣa gbogbo ara ẹ yankan-yankan, leyii to fihan pe ki i ṣe omi lo mu ku, awọn amookunṣika kan ni wọn pitu buruku naa.
Eerin ku, wahala ba ọbẹ, iku aimọdi yii mu kawọn ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ itọpinpin ati ifimufinlẹ, wọn fẹẹ mọ’bi ti ina oro naa ti jo wa.
Ṣebi o yẹ kẹni to mọ nnkan i fi pamọ buruburu maa ranti ẹni to mọ nnkan i wa dori okodoro, lẹyin nnkan bii oṣu meji, isapa awọn ọlọpaa-inu yii seeso rere, ọwọ tẹ ọkan ninu awọn afurasi adigunjale yii, Damilọla Famoriyọ, lọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun 2023 yii, ile rẹ to wa ni New site, laduugbo Awosan Fakalẹ, Ikorodu, nipinlẹ Eko ni wọn tọpasẹ ẹ wa, foonu oloogbe to wa lọwọ ẹ lo ṣamọna wọn, bi wọn si ṣe yọ si i, wọn ba foonu naa lọwọ ẹ, ni wọn ba fi pampẹ ọba gbe e.
Bọwọ ṣe tẹ Damilọla yii mu ki wọn tete ri aburo ẹ ti wọn jọ ṣiṣẹẹbi ọhun, Ikorodu kan naa lawọn mejeeji n gbe, ni wọn ba lọọ mu Emmanuel Abiọdun ni ile ẹ to wa ni Road 1, Block A, adugbo Máyà, n’Ikorodu, awọn mejeeji ba dero ahamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ.
Ninu akọsilẹ ti ọkọọkan wọn kọ ni teṣan, wọn fẹnu ara wọn jẹwọ pe loootọ, awọn lawọn pa Oloogbe Amos, ati pe iṣẹ adigunjale lawọn n ṣe, wọn ni mọlẹbi kan naa lawọn, ọkan jẹ ọmọ ẹgbọn, ekeji jẹ ọmọ aburo.
Wọn tun jẹwọ pe ikọ adigunjale awọn ki i ṣe elero pupọ o, meji pere naa ni, wọn ni agbegbe Ijẹbu-Ode ati ayika ẹ lawọn yan laayo ti awọn ti n pitu fun awọn ọlọkada ati oni-Maruwa, bo tilẹ jẹ pe Ikorodu lawọn n gbe.
Lori ti Amos ti wọn pa yii, wọn jẹwọ pe niṣe lawọn haaya oni-Maruwa naa pe ko bawọn ko ire oko diẹ kan lati Agoro de igboro Ijẹbu-Ode, awọn si jọ dunaadura owo. Bi awọn ṣe n lọ lọna lawọn ri i pe kẹkẹ rẹ yii joju ni gbese, o duro digbi nilẹ, lawọn ba da a duro, awọn si le e bọọlẹ lati ji kẹkẹ naa gbe. Ṣugbọn ojubọrọ kọ la fi i gba ọmọ lọwọ ekurọ, Chukwuka naa ṣe bii ọkunrin, wọn lo bawọn wọya ija, o si taagun gidi, eyi lo mu kawọn fibinu ṣa a ladaa ṣakaṣaka titi to fi ku, lawọn ba wọ oku ẹ ju somi, pẹlu ireti pe odo naa yoo gbe oku ẹ jinna rere, awọn o mọ pe niṣe loku naa de eti omi duro. Awọn ọlọpaa tun bi wọn pe o ti to kẹkẹ Maruwa meloo ti wọn ti ji gbe bẹẹ, wọn ni ko ti i pọ, mẹjọ pere ni, ti oloogbe yii naa lo ṣikẹjọ.
Wọn tun jẹwọ pe agbegbe Ikorodu lawọn maa n ta kẹkẹ tawọn ba ji gbe si, tori awọn onibaara ti wọn maa sanwo loju-ẹsẹ ti wa ni sẹpẹ fawọn, ko si lọ-ka-bọ nibẹ rara.
Awọn ọdaju ẹda yii lawọn o ki i lo ibọn fi jale ni tawọn, ada ati ọbẹ, aṣooro atawọn nnkan ija mi-in lawọn maa n lo.
Awọn ọlọpaa ti lọọ gbọn ile awọn mejeeji yii yẹbẹyẹbẹ, wọn ri ada ti wọn fi pa Amos Chukwuka, atawọn nnkan ija bii ọbẹ, ati oogun abẹnugọngọ nibẹ loootọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, to fiṣẹlẹ yii to Alaroye leti ninu atẹjade kan, sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ naa. O ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Frank Mba, ti paṣẹ pe lẹyin iwadii to lọọrin, awọn maa taari wọn siwaju adajọ.