Ileeṣẹ panapana gbe oku iyaagba kan jade nibi ijamba ina n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji yii, ni ajọ panapana ni Kwara gbe oku iyaagba ẹni ọgọrin ọdun kan jade nibi iṣẹlẹ ijamba ina to waye ni Ojule ketalelogoji, Opopona Adegboye, lẹyin Sẹkiteriati ijọba apapọ to wa lagbegbe Fate, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ilọrin (East), niluu Ilọrin.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ panapana nipinlẹ ọhun, Hassan Hakeem Adekunle, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji yii, lo ti sọ pe ajọ naa gba ipe pajawiri lati ọdọ ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Oni, ni nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ Aiku, lagbegbe Fate, niluu Ilọrin, pe ina ti n sọsẹ ni ile alaja meji kan, loju-ẹsẹ lo ni awọn sare debi iṣẹlẹ ọhun.

Hakeem ni nitori pe wọn ko tete kan si ajọ panapana, ina ti ba ọpọ dukia jẹ jinna ninu ile oni fulaati mẹrin ọhun, fulaati kan ti jona kanlẹ, ninu eyi to jona ọhun ni wọn ti ri oku iya ẹni ọgọrin ọdun kan gbe jade.

Bakan naa ni ọpọ dukia tun ṣofo nibi ijamba ina miiran to waye nileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Ọlanilẹkun, ni G.R.A, laduugbọ Oyeleke Memorial College, Ọffa, niluu Ọffa, lọjọ Aiku, Sannde, yii kan naa ninu ile oni fulaati mẹjọ. Fulaati kan lo jona, ọpọ dukia si segbe latari ina ẹlẹntiriiki to ṣẹju.

Adari ajọ panapana ni Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ naa ki wọn maa wa ni oju lalakan fi n ṣọri, ki wọn si yago fun gbogbo ohun to le ṣokunfa ijamba.

Leave a Reply