Atiku Abubakar lawa eeyan Oke-Ọya yoo dibo fun-Muhammad

Faith Adebọla

Ọkan pataki ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Arewa Consultative Forum, Alaaji Mahammad Yakubu, ti kede pe oludije funpo aarẹ ti ẹgbẹ naa fọwọ si, tawọn eeyan agbegbe Oke-Ọya yoo dibo wọn fun lasiko eto idibo gbogbogboo to n bọ yii ni Alaaji Atiku Abubakar, ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party.

Yakubu, to jẹ oluranlọwọ apapọ fun ẹgbẹ ACF sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu Keji ta a wa yii, lasiko ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn oniroyin kan to waye nile ẹgbẹ wọn ọhun to wa ni Ojule kọkanla, ọna Sokoto, niluu Kaduna, nipinlẹ Kaduna.

Ọkan pataki ninu awọn ẹgbẹ to so awọn alẹnulọrọ lagbo oṣelu lapa Oke-Ọya orileede yii papọ ni ẹgbẹ Arewa Consultative Forum.

Ninu ọrọ rẹ, Yakubu ni awọn ọrọ ati atẹjade ti awọn agbaagba pataki nilẹ Hausa bii Alaaji Zango Daura ati Ọjọgbọn Ango Abdullahi, ati bẹẹ bẹẹ lọ gbe jade lẹnu lọọlọọ yii ti fihan pe Atiku ni iha Ariwa n ba lọ lasiko idibo yii.

O ni idi tawọn eeyan Ariwa fi pinnu lati ṣatilẹyin fun Atiku ki i ṣe tori pe o wa lati agbegbe naa, amọ nitori oun lo ni iriri ati agbara lati gbe orileede yii delẹ ileri ni.

“Awọn iṣẹlẹ kan to ti waye lorileede yii lo mu ka da ẹgbẹ ACF silẹ. Ohun to maa ṣe awọn eeyan agbegbe Oke-Ọya lanfaani ni ACF n ja fun, pẹlu bo si ṣe ku ọjọ diẹ ta a maa dibo yan awọn adari wa yii, awọn agbaagba wa, awọn aṣaaju bii Alaaji Sani Zango Daura, Danmasanin Daura, Ọjọgbọn Ango Abdullahi ti sọ ibi ta a n lọ fun wa. Atiku ni oludije wa l’Oke-Ọya, ibi ti gbogbo wa si n lọ niyẹn.

Oun ni oludije ti eyi to pọ ju lọ ninu awọn oludibo Oke-Ọya maa dibo fun. Tori ẹ ni mo ṣe pe ipade awọn oniroyin yii, ti ibeere eyikeyii ba wa ka le tete dahun ẹ. Emi naa ni Alakoojọ ẹgbẹ Atiku/Okowa Patriots.” Gẹgẹ bo ṣe wi

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni Ango Abdullahi sọ l’Abuja pe o ṣi ku ọdun mẹrin ti awọn eeyan Oke-Ọya yoo fi ṣakoso orileede Naijiria ki ipo aarẹ too ṣi lọ si agbegbe mi-in.

Leave a Reply