Ile-ẹjọ ni ki wọn lọọ yẹgi fun Ọlabọde to lu iyawo rẹ pa toyun toyun l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ giga to fikalẹ siluu Akurẹ ti ni ki wọn lọọ yẹgi fun Oluwaṣeun Ọlabọde lori ẹsun pe o lu iyawo rẹ, Abilekọ Blessing Adaeze Ọlabọde, pa toyun toyun latari ede aiyede ranpẹ to waye laarin wọn.

Iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun 2020, ninu ile ti wọn n gbe lagbegbe Oke-Ọgba, l’Akurẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti awa gbọ, ọdun 2014 ni Ọlabọde ati iyawo rẹ ti fẹ ara wọn, ọmọ kan pere lo si wa laarin wọn, oyun ọmọ keji lo ṣi wa ninu ikun rẹ eyi ti ko ti i bi titi ọlọ́jọ́ fi de si i.

Asunwọn owo kan naa ni tọkọ-taya ọhun jọ n ko owo pamọ si, owo kan ti Ọlabọde lọọ gba ninu asunwọn banki wọn lati fi ra ounjẹ sile lasiko arun Kòró lo da wahala silẹ.

Ọkunrin to ṣẹṣẹ le lọmọ ọgbọn ọdun ọhun ni wọn lo binu la apola igi mọ iyawo rẹ nikun lai wo ti oyun to wa ninu rẹ mọ ọn lara, leyii to mu ko bẹrẹ si i rọbi tipatipa.

Ile-iwosan ijọba to wa l’Akurẹ lo kọkọ sare gbe obinrin naa lọ fun itọju, nigba to ri i pe apa awọn dokita ibẹ ko fẹẹ ka a lo tun gbe e, o di ọsibitu ijọba apapọ to wa niluu Ọwọ.

Ọsibitu yii ni wọn ti fi iṣẹ abẹ gbe ọmọ inu rẹ jade lokuu, ọsẹ kan lẹyin eyi ni wọn loun funra rẹ dagbere faye latari ibi to fi ṣeṣe nigba ti ọkọ rẹ la igi mọ ọn ninu.

Ọjọ karun-un, oṣu Karun-un, ọdun 2020, ni wọn lọọ fi iṣẹlẹ yii to awọn agbofinro leti nipasẹ iwe ẹhonu kan ti Dokita Henry Orumen to jẹ agbẹjọro awọn obi Oloogbe fi ṣọwọ si kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo nigba naa.

Ko pẹ rara tọrọ ọkunrin naa fi de kootu, nibi ti wọn ti fẹsun ipaniyan atawọn ẹsun mi-in kan an.

Baba iyawo, Ọgbẹni Anya, ni wọn kọkọ pe lati waa sọ ohun to mọ nipa ibaṣepọ to wa laarin ọmọ rẹ ati olujẹjọ, ninu alaye rẹ lo ti fidi rẹ mulẹ pe ọjọ pẹ ti Ọlabọde ti n fiya jẹ ọmọ oun.

O ni oloogbe ọhun ti figba kan gbiyanju lati gbe oogun jẹ latari awọn iya to n foju wina lati ọdọ ọkọ ati ìyá-ọkọ rẹ.

Ẹri iya oloogbe atawọn ẹlẹrii bii mẹrin mi-in ti wọn tun sọrọ ko fi bẹẹ yàtọ̀ sira wọn, gbogbo wọn ni wọn fidi rẹ mulẹ ni kootu pe loootọ ni ọkunrin naa kundun ati maa lu iyawo rẹ bii ilu bẹmbẹ.

Iya oloogbe, Abilekọ Anya, ni ọmọ oun jẹwọ foun nileewosan ko too ku pe ọkọ oun lo la igi mọ oun nikun.

Dokita to ṣayewo oku Adaeze, O E. Pelemọ, ni iku iya ọlọmọ kan ọhun waye latari ọgbẹ to wa ninu rẹ, eyi to mu ko maa ṣe ẹjẹ sinu, bakan naa lo ni ọkan-o-jọkan egbo loun tun ṣakiyesi ni ẹgbẹ kan ninu ikun rẹ lọhun-un.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ A. Adebusoye ni olupẹjọ ati gbogbo awọn ẹlẹrii to ko wa si kootu ni wọn fidi ẹri wọn mulẹ kọja ṣiṣe iyemeji, o waa paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun olujẹjọ titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.

Leave a Reply