Ọrẹoluwa Adedeji
Ọrọ ibo ti wọn di ni Katsina yoo ya awọn eeyan lẹnu, nitori pẹlu gbogbo atilẹyin ti Aarẹ Muhammadu Buhari n ṣe fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ibo ti wọn di ni ipinlẹ rẹ ko fi eleyii han rara. Ni agbegbe Daura ti Buhari ti wa, inakuna ni Abubakar Atiku ti i ṣe ondupo aarẹ awọn PDP na Tinubu, koda o tun na Rabiu Kwakwanso ti ẹgbẹ NNPP naa mọ ọn.
Ẹni to dari eto akoso ibo naa, Ọjọgbọn Muazu Giussau, lo kede eyi ni bii aago meta oru ọjọ aje yii, to si ṣalaye pe o le ni miliọnu kan awọn eeyan ti wọn dibo nibẹ, Atiku si fẹrẹ mu to idaji apapọ gbogbo ibo ti wọn di naa, ti Tinubu, Rabiu Kwakwanzo ti ẹgbẹ NNPP ati Peter Obi si pin eyi to ku mọ ara wọn lọwọ. Ohun to mu iyanu wa nidii eyi ni pe ọgọọrọ eeyan lo ti gba pe niwọn igba to ti jẹ Katsina ni Buhari ti wa, to si jẹ oun ni olori pata fun ẹgbẹ APC, akunfaya ni ibo ti wọn yoo di fun Tinubu nibẹ yoo jẹ, wọn si ti ka ipinlẹ naa mọ ara eyi ti Tinubu maa ni.
Nigba ti awọn eeyan n pariwo paapaa pe o da bii pe Buahri ko fẹẹ ṣe atilẹyin fun Tinubu yii, nigba ti ọkunrin naa dibo rẹ tan ni ọjọ Abamẹta to kọja, niṣe lo na iwe idibo rẹ soke ni gbangba, to ni ki gbogbo eeyan waa wo ohun ti oun di nibo, ki wọn waa wo ẹgbẹ ati ẹni ti oun dibo oun fun, wọn yoo ti ri i pe ti Tinubu loun n ṣe lọjọkọjọ. Ọrọ naa ko tilẹ tẹ awọn lọọya lọrun, wọn ni ko bofin mu fun Buhari lati ṣe iyẹn nile idibo, wọn ni bii pe o n ṣe kampeeni fun Tinubu ni.
Ṣugbọn pẹlu gbogbo ẹ naa, ibo ti wọn di ni Katsina burẹkẹ, nibi ti Atiku ti le awọn Tinubu ati Kwakwanso lọ. Ọjọgbọn Muazu Abubakar Gusau to kede esi ibo yii ni oun dupẹ lọwọ gbogbo awọn ara Katsina, nitori wọn dibo wọn wọọrọ, ko si ibi kan bayii ti wọn ti ja tabi ti awọn ti gbọ ariwo pe awọn tọọgi kọ lu wọn nibi kan, o ni bo ti yẹ ki gbogbo ibo ri niyẹn. Idunnu to si tun wa nibẹ ni pe gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu nla nla ti wọn wa nibẹ ni wọn fọwọ si esi idibo naa, wọn ni bo ti ri gan-an niyẹn.