Ọlawale Ajao, Ibadan
Ti wọn ba n powe pe ẹnikan ki i jẹ kilẹ o fẹ, nibomi-in lowe yii ti nitumọ, ki i ṣe lọdọ ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ, All Progressives Congress (APC), ipinlẹ Ọyọ, ẹgbẹ to da nikan ko gbogbo ipo sẹnetọ mẹtẹẹta ti yoo maa ṣoju ipinlẹ Ọyọ mọ gbogbo ẹgbẹ oṣelu yooku lọwọ.
Orukọ awọn oloriire naa ni Sẹneto Fatai Buhari to n ṣoju ẹkun dibo Ariwa ipinlẹ Ọyọ, Alhaji Yunus Akintunde (Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ọyọ) ati Amofin Sarafadeen Alli, ẹni ti yoo maa ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin apapọ kin-in-ni niluu Abuja, lati inu oṣu Karun-un, ọdun yii lọ.
Fatai Buhari naa ni sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo rẹ, Ariwa ipinlẹ Ọyọ lọwọlọwọ.
Sarafadeen Alli naa ti gbooorun ipo ọhun ri, o wa lara awọn to wọle idibo sẹnetọ lọdun 1992, ṣugbọn ti idarudapọ eto oṣelu “June 12” ọdun 1993 ko jẹ ki wọn le bura fun wọn. Yunus Akintunde nikan ni ko ti i gbooorun ipo ọhun ri ninu awọn mẹtẹẹta.
Buhari, ẹni ti apapọ ibo rẹ jẹ ẹẹdẹgbẹrun ati mejidinlọgọrin (90,078) lo fagba han Akinwale Akinwọle, ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to ṣe ipo keji, ẹni to ni ibo ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrin ati mẹrinlelọgbọn (77,034) nigba ti Ọnarebu Shina Peller to ṣe ipo kẹta ni ibo ẹgbẹrun mẹrinlelaaadọta ati ojilelẹgbẹrin o din mẹfa (77, 034).
Ibo ẹgbẹrun mọkanlelaaadọfa ati ẹẹdẹgbẹta o le mẹtala (111,513) l’Amofin Sarafadeen Alli ni, iyẹn lo fi gba ipo sẹnetọ ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ mọ Mọgaji Joseph Tegbe, ọmọ oye ẹgbẹ oṣelu PDP, to ni ibo ẹgbẹrun mejilelaaadọrun-un ati ọrinlenirinwo o le ẹyọ kan (92,481) lọwọ.
Iha Guusu yii lo jẹ ẹkun idibo gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde.
Yunus Akintunde, ọmọ bibi ilu Ọyọ, to wọle idibo ẹkun idibo Aarin Gbungbun ipinlẹ Ọyọ, lo la Oloye Bisi Ilaka, ọmọ oye ẹgbẹ oṣelu PDP ati Ẹnjinnia Nurudeen Faozey ti ẹgbẹ oṣelu Akọọdu mọlẹ ninu ijijadupo oṣelu ọhun.
Ibo ẹgbẹrun mejidinlaaadọfa ati ọrinlelẹgbẹrin o din mẹrin (108,776) l’Akintunde ni; Oloye Ilaka, ọmọ ẹgbẹ PDP to pọwọ le e, ni ibo (101,213) nigba ti Faozey to dije lorukọ Akọọdu ni ibo ẹgbẹrun mọkanlelogoji ati ojilelẹẹẹdẹgbẹta ole mẹta (41,743).
Ninu atẹjade ọtọọtọ, awọn oludije mẹtẹẹta ti dupẹ lọwọ awọn ara ipinlẹ Ọyọ fun atilẹyin wọn fun ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ ninu idibo naa.