Adewumi Adegoke
Nitori esi idibo aarẹ nipinlẹ Eko ko ṣe ṣenuure, oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti ranṣẹ si awọn ololufẹ rẹ pe ki wọn ni suuru, ki wọn fọkan balẹ, ki wọn si ma ṣe hu iwa ti yoo da wahala silẹ tabi to le da omi alaafia ipinlẹ Eko ru.
Tinubu sọrọ yii ninu atẹjade kan ti Oludari eto iroyin rẹ
lori ipo aarẹ, Bayọ Ọnanuga, gbe sita lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji yii.
Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ yii ni ki awọn eeyan naa ma ṣe binu rara pẹlu bi ẹgbẹ oṣelu alatako, iyẹn ẹgbẹ Labour, ṣe jawe olubori ninu idibo sipo aarẹ nipinlẹ Eko, o ni adun ijọba awa-ara-wa naa ni pe onikaluku eeyan lo ni anfaani lati dibo fun ẹnikẹni to ba wu wọn.
Ọkunrin naa ni gẹgẹ bii olufẹ ijọba tiwa-n-tiwa, o pọn dandan fun oun lati gba esi idibo yoowu to ba waye, boya oun yege tabi oun ko yege.
Aṣiwaju ni inu ohun ko dun si gbogbo wahala ati jagidijagan ati rogbodiyan to ṣẹlẹ niluu Eko ati bi awọn kan ṣe doju ija kọ ẹya Igbo. O bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, o si kilọ fun awọn ti wọn n ṣe bẹẹ ki wọn dawọ re duro. O ni ko yẹ ko si akọlu si ẹya yoowu ko jẹ nipinlẹ Eko.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji yii, ni ajọ eleto idibo ti ipinlẹ Eko kede pe oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, lo jawe olubori nipinlẹ Eko pẹlu bi iye awọn eeyan to dibo fun un ṣe ju ti Tinubu lọ, bo tilẹ jẹ pe ijọba ibilẹ ti Tinubu ti wọle ju tiẹ lọ.