Ọrẹoluwa Adedeji
Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni awọn ọlọpaa nawọ gan olori awọn ọmọ ile to pọ ju lọ nileegbimọ aṣoju-ṣofin to n ṣoju Dguwa/Tudun Wada, Alhassan Ado Doguwa, ni papakọ ofurufu Aminu Kano, to wa niluu Kano, fẹsun ipaniyan. Wọn lẹmii eeyan mẹfa lo ti tọwọ ọkunrin naa bọ.
ALAROYE gbọ pe ọkunrin aṣofin yii lo ṣaaju awọn kan ti wọn ṣe akọlu si ọfiisi ajọ eleto idibo ni agbegbe idibo rẹ lasiko ti wọn n ko esi idibo awọn aṣoju-ṣofin agbegbe naa jọ nibi eto idibo aarẹ ati tawọn aṣofin to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, leyii to yọri si iku eeyan mẹta. Wahala naa si pọ debii pe niṣe ni wọn ni wọn gbe ibọn si oṣiṣẹ ajọ eleto idibo to wa nibẹ leti, ti wọn ni ko kede Doguwa gẹgẹ bii aṣofin to wọle ni adugbo naa tipa tikuuku.
Bakan naa ni wọn lo mọ si bi wọn ṣe dana sun ile ẹgbẹ oṣelu NNPP, to wa ni Tundun Wada. Awọn ọlọpaa ni eeyan mẹta lo ku nile ẹgbe awọn ẹgbẹ oṣelu yii.
Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano, Abdullahi Haruna Kiyawa, ni loootọ ni awọn agbofinro ti mu ọkunrin to jẹ olori awọn ọmọ ẹgbẹ to pọ ju lọ nileegbimọ aṣoju-ṣofin yii fun ẹsun ipaniyan. Wọn ni oun lo ṣaaju awọn tọọgi to lọọ dana sun ile-ẹgbẹ NNPP. Bẹẹ ni wọn lo tun gba ibọn ọkan ninu awon ẹṣọ rẹ, to si bẹrẹ si i yin in mọ awọn eeyan. O ni awọn ti mu un fun ẹsun ipaniyan ati lilo ohun ija lọna ti ko tọ, iwadii si ti bẹrẹ lati mọ ipa to ko ninu iṣẹlẹ ọhun.
O waa ṣeleri pe awọn yoo ṣe iwadii to lọọrin lori iṣẹlẹ naa ki igbeṣẹ kankan too waye lori rẹ.