Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ṣe lọpọ awọn oluworan to wa nile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe NEPA, niluu Akurẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, la ẹnu wọn ti wọn ko si le pa a de mọ nigba ti wọn gbọ ọrọ aṣiri to n jade lati ẹnu ọmọdekunrin kan torukọ rẹ n jẹ Lekan Mustapha, lori ọna ti wọn n gba ji awọn ọmọ ọlọmọ gbe, ti wọn si n ta wọn ni itakuta siluu Ikorodu, nipinlẹ Eko.
Inu oṣu Keji, to ṣẹṣẹ pari yii lọwọ tẹ ọmọdekunrin ẹni ọdun mẹrindinlogun ọhun ati ọga rẹ, Alfa Zulum Yisa, niluu Ọka Akoko.
Nigba to n salaye bi ọrọ ṣe jẹ, Lekan ni ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, loun ti ṣe alabaapade Yisa ni kete tawọn obi oun ku lọdun diẹ sẹyin, ti awọn mejeeji si jọ fi ẹsẹ rin lati Ilọrin titi tawọn fi de agbegbe Akoko.
O ni iṣẹ ajọmọgbe lawọn yan laayo ni kete tawọn gunlẹ si ilu ti awọn fi ṣe ibugbe yii.
Bisikiiti lo ni oun fi maa n tan awọn ọmọ ọlọmọ lọ sọdọ Yisa, ti wọn ba si ti n de ọdọ rẹ lo ni yoo fi oruka ẹrẹ kan to wa lọwọ rẹ lu wọn laya, ti awọn ọmọ ọhun ko si ni i mọ ohun ti wọn n ṣe mọ titi ti awọn yoo fi ko wọn lọ sọdọ Afaa Musulumi kan to wa n’Ikorodu, nibi ti awọn n ta wọn si.
Lekan ni o ti to bii ọmọ mẹsan-an ti wọn ti ko si pampẹ awọn, ti awọn si ti lọọ lu ta ni gbanjo ki ọwọ awọn ẹṣọ Amọtẹkun too pada tẹ awọn laipẹ yii.
O ni ki i ṣe Ọka Akoko nikan lawọn ti n ṣiṣẹ ibi yii, ibikíbi ti awọn ba ti ba ara awọn lawọn ti maa n ji ọmọ gbe.
Nigba ti wọn beere lọwọ Yisa to jẹ ọga rẹ boya ootọ ni gbogbo ẹsun ti ọmọọṣẹ rẹ fi kan an, ṣe lọkunrin naa sẹ kanlẹ, o ni ko sohun to jọ bẹẹ.
Ninu ọrọ agbẹjọro ijọba to jẹ olupẹjọ, Amofin O. F. Akeredolu, o ni awọn mejeeji ti kọkọ jẹwọ pe loootọ lawọn n ji ọmọ gbe.
Akeredolu ni awọn mejeeji ni wọn ti ṣẹ si abala ofin kẹta ati ikẹfa, ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2010, eyi to ta ko iwa ijinigbe.
O waa bẹ adajọ pe ko paṣẹ fifi awọn mejeeji pamọ sinu ọgba ẹwọn titi ti imọran yoo fi wa lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Damilọla Ṣekoni gba ẹbẹ agbefọba wọle, o ni ki Yisa ṣi wa lahaamọ ọgba ẹwọn Olokuta, ki Lekan to jẹ ọmọọṣẹ rẹ lọọ maa ṣe faaji tirẹ ninu ọgba ẹwọn awọn ọmọde to wa loju ọna marosẹ Ondo, niluu Akurẹ.
Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, lo ni igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.