Ọlọpaa yii yinbọn para ẹ lẹyin to pa ọrẹbinrin ẹ tan ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹji, oṣu Keta, ni Sajẹnti ọlọpaa kan, Ọlalere Michael, ṣeku pa ọrẹbinrin rẹ kan, Tọsin, toun naa si pada yinbọn pa ara rẹ ninu ọgba ileewe Chapel of Redemption (UMCA), to wa lagbegbe Gaa Akanbi, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ owurọ ni iṣẹlẹ naa waye ninu ọgba ileewe alakọbẹrẹ Chapel of Redemption (UMCA), Agba Dam Housing Estate, Gaa Akanbi, niluu Ilọrin. Wọn ni ọlọpaa yii ti n lepa ẹmi arabinrin yii tipẹ, kọda, wọn lo wa a lọ si ile mọlẹbi oloogbe naa lagbegbe Opopona Ẹrin-Ile, Gaa Akanbi, pẹlu ada, nitori edeiyede tẹnikẹni ko ti i le sọ to wa laarin wọn, ṣugbọn ko ri i nibẹ, ko too wa ṣeku pa a l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii.

Lasiko ti oloogbe yii n gbe ọmọ rẹ lọ sileewe ni ọlọpaa ọhun lọọ ka a mọ ileewe naa, to si pa a sibẹ.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara, CP Paul Odama, ti dari ikọ ọlọpaa sibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si ti ko oku awọn mejeeji lọ sileewosan ẹkọsẹ Fasiti Yunifasiti Ilọrin, (UITH), ti iwadii si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply