O san ki Atiku pada si Dubai rẹ, ti ko ba gba pe emi ni mo wọle ibo aarẹ- Tinubu

Monisọla Saka

Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti i ṣe aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ti sọ fun ojugba ẹ lẹgbẹ oṣelu alatako, PDP, Alaaji Atiku Abubakar, pe ko kọri si Dubai ẹ lọwọ ẹrọ, ti ko ba ti fara mọ pe oun loun wọle ibo aarẹ.

O ni dipo ki igbakeji aarẹ ilẹ wa tẹlẹ naa maa dupẹ pe oun ṣe ipo keji ninu ibo to waye lọjọ Satide to kọja yii, to jẹ pe Ọlọrun lo ba a ṣe e, nitori ki ba ma ti rọwọ mu to ibi to de duro yẹn.

Tinubu lo sọrọ yii ninu atẹjade ti agbẹnusọ awọn igbimọ eleto ipolongo ibo rẹ, to tun jẹ minisita kekere fọrọ awọn oṣiṣẹ igbanisiṣẹ, Festus Keyamo, gbe jade. Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni gbogbo nnkan ti Atiku ba n ṣe nisinyii, aṣekagba ati aṣegbẹyin ẹ ni.

O ni, “Ninu nnkan ta a le ṣapejuwe gẹgẹ bii ẹṣin ti ki i kọ ere asarele, ni ariwo ti Atiku n pa. Nirọlẹ yii ni Alaaji Atiku Abubakar tun ba awọn oniroyin sọrọ pe eto idibo ọdun 2023 yii ko lọ nirọwọ rọsẹ, bẹẹ lo kun fun awọn iwa agabagebe. O sọ ọrọ banta banta bayii lai ri ẹri kankan fi gbe ọrọ ẹ lẹsẹ, afi koun naa tun maa huwa ainitiju pẹlu bo ṣe maa n gbe fere, lati maa pariwo nnkan tawọn alatilẹyin ẹ n sọ lawọn ori ẹrọ ayelujara kiri. Bakan naa lo tun n fibinu ati ikanra sọ awọn ọrọ ti ko daa ta ko aarẹ tuntun ti ajọ INEC ṣẹṣẹ kede ẹ, Aṣiwaju Bọla Tinubu.

“Dipo ki Atiku gba ilu, ko maa jo, ko si maa dupẹ lọwọ ẹlẹdaa ẹ pe oun tun ṣe daadaa ju bawọn eeyan ṣe lero lọ gẹgẹ bo ṣe ri ipo keji di mu ninu ibo ti wọn ṣẹṣẹ di tan yii. Pẹlu gbogbo wahala ati ariwo lọtun-un losi, ati iyapa oun ija ninu ẹgbẹ wọn, o yẹ koun funra ẹ ti mọ tipẹtipẹ pe oun ko nibi i lọ, wọn yoo si lu oun laludojubolẹ ninu ibo ọhun ni. Gbogbo awọn rogbodiyan inu ẹgbẹ wọn yii lo yẹ koun gan-an ti mọ pe o ṣee ṣe ko ṣokunfa koun mu ipo kẹta tabi ikẹrin.

Ti Atiku ba waa kọ, to loun atawọn mi-in ti wọn fidi-rẹmi ko ni i gba fun oriire aarẹ tuntun, Tinubu, ati ọwọ ifẹ to na lati ko wọn mọra, nnkan to ku fun un, to si kere ju to le ṣe, naa ni lati pada siluu Dubai ẹ jẹẹjẹ, ilu to jẹ pe o ti sọ di ile rẹ pataki yii”.

Tinubu tẹsiwaju pe nitori bi Atiku ṣe yẹba adehun ti wọn ṣe lati maa gbe awọn ipo pataki lẹgbẹ wọn yika awọn ẹkun lorilẹ-ede yii, pẹlu bo ṣe ta ku wọnnle pe dandan gbọn ni koun di aarẹ, ti ko si tun faaye ipo alaga silẹ lati bọ si iha ibomi-in lo ṣatọna iṣubu ẹ. O ni koda lẹyin to gbegba oroke ninu ibo abẹle wọn, ti wọn si fa a kalẹ gẹgẹ bii ẹni ti yoo dupo aarẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP ko yee foju awọn aṣaaju lati ẹkun Guusu ilẹ yii ri rẹdẹrẹdẹ, pẹlu bi wọn ṣe tun duro lori pe awọn tawọn wa lati apa Ariwa lawọn yoo tun di ipo alaga ẹgbẹ naa mu.

“Lai si ani-ani, eleyii lo ṣokunfa iyapa awọn gomina marun-un kan tinu n bi, ati bi wọn ṣe kẹyin si ẹgbẹ ati gbogbo eto inu ẹgbẹ wọn pata, ti wọn si tun n polongo ta ko Atiku. Bi Atiku ṣe kuna lati fidi iṣọkan mulẹ ninu ẹgbẹ wọn, ti ko si wa nnkan ṣe si fa-n-fa to bẹ silẹ lẹyin ibo abẹle wọn lo fa ijakulẹ rẹ”.

“Fun idi eyi, awọn ọmọ Naijiria ti ri ọrọ Atiku bii eyi to n da ṣe funra ẹ, ati ẹni to n da ara ẹ laamu. Nitori lati bii ọgbọn ọdun sẹyin to ti n gbegba ibo aarẹ, ati bo ṣe n ja lulẹ, tawọn ọmọ Naijiria si n kọ ọ niwaju ati lẹyin, o yẹ ko han si i pe oun ko yẹ lẹni ti wọn n dibo fun, ilu ko si fẹ oun loye. Bẹẹ naa ni gbogbo aṣiri owo ilu to ko da si apo ara rẹ lasiko to wa nipo igbakeji. ”

Tinubu waa ke si Atiku pe oun naa wa ni igbaradi lori erongba rẹ lati ta ko abajade esi idibo aarẹ. Wọn lawọn ti ṣetan lati koju iru ẹjọ yoowu tabi ọna yoowu to ba fẹẹ gbe e gba lọjọkọjọ ati nigbakuugba.

Leave a Reply