Jọkẹ Amọri
Titi ba a ṣe n sọ yii ni awọn eeyan ṣi n ba mọlẹbi olori orileede wa tẹlẹ, Ibrahim Sani Abacha, kẹdun. Eyi ko sẹyin bi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ṣe fo sanlẹ, to ku lojiji.
ALAROYE gbọ pe Abdullahi Abacha yii ti oju oorun de oju iku ni nile rẹ to wa ni Opopona Nelson Mandella, niluu Abuja. Wọn ni ko si ohun to ṣe e ko too wọle sun lalẹ ọjọ naa, bẹẹ ni ki i ṣe pe aisan kankan ti wa lara rẹ ṣaaju asiko ti iku mu un lọ yii, gẹgẹ bi ọkan ninu awọn mọlẹbi ṣe sọ, o kan sun naa ni, nigba to si di owurọ ọjọ keji ni wọn ri i pe o ti sọda sodikeji. A gbọ pe ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji yii lo wa ni ipo kẹjọ ninu awọn ọmọ mẹsan-an ti Oloogbe Sanni Abacha fi saye lọ.
Ẹgbọn oloogbe naa, Fatimah-Gumsu Abacha-Buni to jẹ iyawo gomina ipinlẹ Yobe, lo kede ọrọ naa lori ikanni abẹyẹfo (twitter) rẹ pe, ‘‘Inna lillahi wa inna ilaehi rajiun (Ohun to daju ni pe ọdọ Allah ni a ti wa, ọdọ rẹ naa ni a oo pada si). Mo padanu aburo mi, Abdullahi Sani Abacha. Oju oorun lo ti de oju iku. Ki Ọlọrun Allah foju pa aṣiṣe rẹ rẹ, ko si tẹ ẹ si Aljanah onidẹra. Ẹ jọwọ, ẹ ba mi ranti rẹ ninu adura.
Irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrin, oṣu yii, ni wọn ni eto isinku rẹ yoo waye ni mọṣalaṣi nla to wa niluu Abuja laago mẹrin irọlẹ.