Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Bi iku ile ko pa ni, tode ko le ri ni pa. Bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri pẹlu ọmọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Lómi Akinbinu, ẹni to gbimọ pọ pẹlu awọn ọrẹ rẹ kan, ti wọn si ji ẹgbọn rẹ, Akinọla Akinbinu, ti wọn jọ jẹ ọmọ iya ati baba kan naa gbe. Lẹyin eyi lo pe awọn mọlẹbi pe ki wọn lọọ wa owo wa, ki wọn si fi sinu asunwọn kan to fi ranṣẹ si wọn ti wọn ba ṣi fẹẹ ri ọmọ wọn yii laaye.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹbi sa ile ati ọna jọ, ti wọn si fowo naa ranṣẹ, ọdaju ọmọkunrin yii tun pa ẹgbọn rẹ yii lẹyin to gbowo tan. Ogun baba wọn ti wọn n ja si wa ninu ohun ti wọn lo tori ẹ pa Akinọla.
Ọwọ ọlọpaa pada tẹ ọmọkunrin yii, ẹsun ti wọn si fi kan an ni pe o mọ nipa bi wọn ṣe ji ẹgbọn rẹ, Akinọla Akinbinu, gbe ninu oko rẹ ti wọn n pe ni Oko Ọparun, eyi to wa nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ondo, ni nnkan bii oṣu kan sẹyin, ti wọn si tun da ẹmi rẹ legbodo lẹyin ti wọn gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira lọwọ awọn ẹbi rẹ.
Lómi ni wọn lo gbimọ-pọ pẹlu awọn janduku ẹgbẹ rẹ kan lati jọ ji ọkunrin ẹni ogoji ọdun naa gbe, to ran an sọrun ọsan gangan lori ọrọ ogun baba wọn to ni o gbẹsẹ le.
ALAROYE gbọ pe iya to bi oloogbe ọhun wa lara awọn to n bẹ awọn ọlọpaa ki wọn ṣi fi Lómi pamọ sọdọ wọn, o ni inu ewu patapata ni ẹmi oun ati ti iyawo Akinọla wa ti wọn ba fi le yọnda afurasi naa lai ti i ri okodoro idi ti wọn fi pa ọmọ oun laipe ọjọ.
Ọlọpaa kan ta a forukọ bo laṣiiri to ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa sọ pe loootọ ni wọn ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin ta a n sọrọ rẹ yii, ti wọn si ti fi i ṣọwọ si olu ileeṣẹ wọn to wa l’Akurẹ, fun ẹkunrẹrẹ iwadii.
Akinọla lawọn oniṣẹẹbi kan ji gbe ninu oko koko rẹ, ti wọn si fi dandan le e fawọn ẹbi rẹ nigba naa lati lọọ san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin Naira sinu asunwọn ileefowopamọ First Bank ati O’pay kan ti wọn fi ṣọwọ si wọn.
Lẹyin ọjọ keje ti wọn ti sanwo ọhun tan ti wọn ṣi n reti asiko ti wọn yoo tu okunrin ọmọ bibi ilu Ondo naa silẹ ni wọn ṣalabaapade oku rẹ nitosi ibi ti wọn ti ji i gbe pẹlu kẹmika buruku kan ti wọn da si i lara.
Lẹyin-o-rẹyin laṣiiri tu pe aburo rẹ lo ṣeku pa a.