Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ti wọ ọkunrin ẹni ọdun marundilogoji kan, Adebayọ Wasiu, lọ sile-ẹjọ Majisireeti kan to wa ni Ado-Ekiti. Ọdaran naa to n gbe ni Ado-Ekiti, lawọn ọlọpaa wọ wa sile-ẹjọ lori ẹsun kan ṣoṣo to rọ mọ ole jija. Iya ewurẹ kan ni wọn ni o lọọ ji gbe.
Agbefọba, Ọgbẹni Elijah Adejare, ṣalaye fun kootu pe ọdaran naa ati ẹnikan to ti sa lọ, ti wọn ko ti i ri bayii ni wọn jọ ṣẹ ẹṣẹ naa lọjọ kejidinlọgbọn, oṣun Keji, ọdun 2023, ni deede aago mẹrin irọlẹ.
O ṣalaye pe odaran naa ati ẹnikan ti awọn ọlọpaa ṣi n wa bayii ni wọn ji iya ewurẹ kan ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna aadọta Naira to jẹ ti Ọgbẹni Abdulraheem Idowu gbe.
Ẹṣẹ yii lo sọ pe o lodi sofin ole jija ti ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ lọdun 2021.
Agbefọba yii waa bẹbẹ pe ki ile-ẹjọ sun ẹjọ naa siwaju ki oun le raaye ko awọn ẹlẹrii oun jọ.
Ṣugbọn ọdaran naa loun ko jẹbi ẹsun naa, bakan naa ni agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Michael Ọlalẹyẹ, bẹ ile-ẹjọ naa pe ko fun onibaara oun ni beeli, pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ.
Onidaajọ Tọmiwa Daramọla fun ọdaran naa ni beeli pẹlu ẹgbẹrun lọna ogun Naira ati ẹlẹrii meji.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ naa siwaju di ọgbọnjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii.