Monisọla Saka
Oludije funpo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), Alaaji Atiku Abubakar, ti ṣa awọn ogunna gbongbo agba agbẹjọro, Senior Advocate of Nigeria, SAN, ti muṣemuṣe wọn da muṣemuṣe mọkandinlogun kan jọ lati ba a rojọ jare ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, nitori esi idibo aarẹ ọdun 2023 yii to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023.
Ṣe wọn ni ijo to ba ka ni lara laa dikuuku jo, ko si ọjẹwẹwẹ ọmọde lọọya to ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ amofin ninu awọn ikọ agbẹjọro ti yoo ṣoju Atiku nile-ẹjọ.
Ni olu ile ipolongo ibo rẹ to wa niluu Abuja, lo ti ba wọn sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun yii, pe ki wọn fidi awọn iwa to ta ko ofin to waye lasiko ibo naa mulẹ, lati le gba ẹtọ awọn ọmọ Naijiria pada fun wọn.
Agba agbẹjọro kan to n jẹ JK Gadzama, lo jẹ adari ikọ awọn lọọya ọhun.
O ṣalaye siwaju si i pe o ṣe pataki fun wọn lati gbe igbesẹ yii, o ni nitori toun ati ẹgbẹ PDP nikan kọ, bi ko ṣe lati tubọ ro ofin ijọba awa-ara-wa lagbara si i, ki wọn si daabo bo o nitori ọjọ ọla wa.
Awọn aworo ṣaṣa lọọya to bẹ lọwẹ ọhun ni, Oloye Chris Uche, Paul Usoro, Tayọ Jẹgẹdẹ, Ken Mozia, Oloye Mike Ozekhome, Mahmood Magaji, Joe Abraham, Chukwuma Umeh, Garba Tetengi, Oloye Emeka Etiaba, Oloye Goddy Uche, Ọjọgbọn Maxwell Gidado, to fi mọ oludamọran lori ọrọ ofin fẹgbẹ oṣelu PDP, A. K. Ajibade, O. M. Atoyebi, Nella Rabana, Paul Ogbole, Nureni Jimoh ati Abdul Ibrahim.
Aṣiwaju Bọla Tinubu, to jẹ ọkan lara awọn mẹta ti wọn n le waju laarin awọn ti wọn n dije funpo aarẹ lorilẹ-ede yii, ni ajọ INEC, kede gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu ibo aarẹ oṣu Keji, ọdun yii. Oludije dupo aarẹ lẹgbẹ PDP, Alaaji Atiku Abubakar, ati ojugba rẹ lẹgbẹ Labour Party, Peter Obi, ti ni awọn ko ni i gba, kaluku wọn ni oun loun ni ibo to pọ ju lọ, eyi lo si mu ki wọn gba ile-ẹjọ lọ lati le beere fun ẹtọ wọn.
Awọn mejeeji yii ni wọn ti dagunla si ọrọ itunu ati ifanimọra ti aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Tinubu, sọ lasiko to n sọrọ akọsọ ẹ lẹyin ti wọn kede ẹ bii aarẹ tuntun ilẹ Naijiria. L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, lẹyin ti wọn kede ẹ bii ẹni to gbegba oroke ninu ibo aarẹ tan lo ke si awọn ti wọn jọ dupo yii pe ki wọn gbaruku ti oun lati le jọ gbe orilẹ-ede yii goke agba.
Lọjọ Iṣẹgun Tusidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta yii, ni Tinubu naa ṣa awọn agbẹjọro ti wọn yoo ja fitafita lati ma ṣe jẹ ki ẹtọ rẹ yii bọ mọ ọn lọwọ jọ, bẹẹ loun naa si ti gba kootu lọ lati gba aṣẹ ko le yẹ gbogbo awọn esi idibo aarẹ to kọja naa wo, eyi ti ile-ẹjọ ti fun un laṣẹ lati ṣe bẹẹ.