Dẹrẹba BRT to ko sẹnu reluwee ni: Ẹ dari ji mi, iṣẹlẹ naa ki i ṣe ẹbi mi

Faith Adebọla

Ṣe ẹ ranti ijamba ọkọ gbọgbọrọ BRT tijọba Eko fi n ko awọn oṣiṣẹ ọba, eyi to ja’na mọ reluwee lẹnu l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta, ta a wa yii, to fọpọ ẹmi ṣofo, tawọn eeyan si fara pa yanna-yanna? Dẹrẹba to wa bọọsi ọhun lọjọ naa, Ọgbẹni Oluwaṣeun Ọṣinbajo, ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44), ti rawọ ẹbẹ sawọn ero inu ọkọ ọhun ti wọn ṣi wa laye pe ki wọn jọwọ, ki wọn fori ji oun lori iṣẹlẹ aburu naa.

Oluwaṣeun, to jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ tijọba gba gẹgẹ bii awakọ l’ẹka to n ri si igbokegbodo ọkọ l’Ekoo, Lagos State Ministry of Transport, lo lọọ fa ara ẹ kalẹ fawọn ọlọpaa lẹyin wakati diẹ tiṣẹlẹ naa waye, bo tilẹ jẹ pe o kọkọ sa lọ loju-ẹsẹ.

Lasiko ti wọn taari ẹ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Eko, nibi tawọn ọtẹlẹmuyẹ ti n wadii okodoro ọrọ, SCID, to wa ni Panti, Yaba, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta yii, nibẹ lọkunrin naa ti ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye fawọn mọlẹbi ẹ kan ti wọn ti waa duro de e, ti wọn si ba a sọrọ.

Bi akọroyin iweeroyin Sun, to lọrọ naa ṣoju oun ṣe wi, dẹrẹba naa ṣalaye pe:

“Haa, ọrọ yii ki i ṣe ẹbi mi, ki i ṣẹbi mi, bawo ni mo ṣe maa ri ewu ti ma a si tori bọ ọ? Bawo ni wọn ṣe maa da mi duro ti mi o ni i duro? Bọọsi yẹn lo yọnu lasiko yẹn. O dun mi pe ijamba yii ṣẹlẹ. O ma ṣe o.

Mo bẹ gbogbo awọn eeyan pe ki wọn dakun fori ji mi, tori Ọlọrun Ọba.”

Bẹẹ ni wọn lọkunrin awakọ yii sọ.

Amọ, awọn kan lara awọn ero inu bọọsi ọhun ti wọn ṣi n gba itọju lọsibitu ni nnkan eelo igbọrọ tawọn eleebo n pe ni earpiece, wa leti dẹrẹba yii nigba tijamba naa fi waye, wọn lo ṣee ṣe ko jẹ pe o n gbọ orin alariwo kan lọwọ ni, tabi ki kinni naa ṣokunfa bi ko ṣe fura si asia pupa tawọn oṣiṣẹ reluwee gbe soke lati da a duro, ti ko si gbọ feere reluwee ọhun.

Oju ọtọ lẹlomi-in fi wo iṣẹlẹ yii ṣaa o. Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ naa to n gba itọju lọwọ sọ pe loootọ niṣẹlẹ yii dẹru baayan, to si ṣe ni laaanu. O ni “o pẹ ti mo ti mọ dẹrẹba yii, ko si ṣẹṣẹ maa wa ọkọ yii, eeyan jẹẹjẹ ni, ohun to rọ lu u to fi wa ọkọ naa bo ṣe wa a laaarọ ọjọ yẹn ṣi n ya mi lẹnu.”

Ṣa, titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ, ijọba ipinlẹ Eko ni eeyan mejidinlọgbọn (32) lara wọn ti mokun daadaa ninu awọn ti wọn fara gba ninu ijamba naa, lẹyin ti wọn gba itọju lọsibitu ni wọn yọnda wọn pe ki wọn maa re’le layọ ati alaafia.

Eeyan mẹjọ la gbọ pe o doloogbe ninu iṣẹlẹ to gbomi loju ẹni ọhun, bo tilẹ jẹ pe ẹni meji lo ku loju-ẹsẹ, tawọn mẹrin si mẹfa mi-in si pada ku loju ọna, ati nigba ti wọn n fun wọn ni itọju pajawiri lọwọ.

Leave a Reply