Monisọla Saka
Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Minisita fọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ṣepade pẹlu awọn eekan eekan, awọn alẹnulọrọ atawọn aṣoju wọọdu idibo lẹkun Alimọṣhọ, nipinlẹ Eko. Eyi ko sẹyin ibo gomina ti yoo waye ni Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii. Nibẹ lo ti rọ awọn eeyan naa lati jọwọ, ṣiṣẹ fun aṣeyọri Gomina Babajide Sanwo-Olu, ninu ibo ti yoo waye ni Satide, ọsẹ yii, ko le baa wọle ẹlẹẹkeji nipinlẹ Eko.
Ninu fidio kan to n ja ranyin kiri ori ayelujara ni ọkunrin naa ti jokoo saarin awọn eeyan kan, to n ba wọn sọrọ, to si n gba wọn niyanju lati ṣatilẹyin fun gomina Eko lasiko idibo ọhun.
Arẹgbẹṣọla, ti i ṣe gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, ati kọmiṣanna fọrọ iṣẹ nipinlẹ Eko, lasiko iṣejọba Aṣiwaju Bọla Tinubu, jẹ ọkan lara awọn aṣaaju pataki lẹgbẹ oṣelu APC lagbegbe ijọba ibilẹ Alimọṣhọ, ati nilẹ Naijiria lapapọ. Oun lo di agbegbe naa mu, fọfọọfọ bii ọmọ ayo ni wọn si maa n fi ibo wọn ṣatilẹyin fun ẹgbẹ APC nigbakugba ti eto idibo ba waye. Afi bi nnkan ṣẹ yiwọ lasiko ibo aarẹ to kọja yii, ti ẹgbẹ APC ko rọwọ mu nibẹ, niṣe ni wọn fidi-rẹmi.
ALAROYE gbọ pe ki wọn ma baa tun ni iru ijakulẹ bẹẹ lasiko idibo gomina ti yoo waye ni Satide yii ni wọn fi ranṣẹ pe ọkunrin naa, ti wọn si bẹ ẹ peko ṣatilẹyin fun ẹgbẹ APC, nitori ọpọ lo gbagbọ pe bi wọn ṣe gba akoso adugbo naa kuro lọwọ rẹ ati ija to wa laarin oun ati awọn aṣaaju ẹgbẹ naa kan niluu Eko, to fi mọ Aṣiwaju Bọla Tinubu, ati Isiaka Oyetọla ti i ṣe gomina Ọṣun tẹlẹ, wa ninu idi ti wọn fi padanu agbegbe naa sọwọ alatako.
Ṣugbọn wọn ni ko si ‘bara ẹ da sọhun-un nidii oṣelu’, Arẹgbẹṣọla ti tun n polongo ibo fun Sanwo-Olu, niṣe lo diidi bẹ awọn eeyan ọhun lati ṣatilẹyin to tọ fun Gomina Sanwo-Olu, ki wọn si sa gbogbo ipa wọn nitori gomina naa ti ṣiṣẹ ribiribi lawọn ẹka ati ileeṣẹ gbogbo nipinlẹ naa, o ni nitori eyi ni ọdun mẹrin mi-in ṣe tun tọ si i, kawọn ohun meremere to n gbe ṣe nipinlẹ Eko le tubọ tẹsiwaju.
Tẹ o ba gbagbe, ninu ibo sipo aarẹ to waye kọja, ẹgbẹ APC ko rọwọ mu ni Alimọṣhọ, Peter Obi, ti ẹgbẹ Labour Party lo wọle nibẹ, bẹẹ ijọba ibilẹ Alimọṣhọ ni ibo rẹ maa n pọ ju, to si maa n tẹwọn ju lọ nipinlẹ Eko.