Ogbologboo adigunjale lọmọkunrin yii, ọkọ ayọkẹlẹ meji lo fibọn gba laarin iṣẹju diẹ l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 Ọjọ-ori gende tẹ ẹ n wo yii ko ju ẹni ọdun mẹrindinlogoji (36) lọ, Dayọ Jimọh lorukọ ẹ, amọ iṣẹ to n fi ibọn ọwọ rẹ ṣe lagbara gidi. Ọkọ ayọkẹlẹ meji loun atawọn ẹmẹwa ẹ meji kan tawọn ọlọpaa ṣi n wa lọwọ, fibọn gba, ibi ti wọn ti n wa ọkọ ọhun niwakuwa lati sa lọ lawọn agbofinro ka wọn mọ tọwọ fi tẹ ẹ.

Ninu alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, ṣe f’Alaroye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta yii, o ni niṣe lawọn adigunjale yii mura bii ero to fẹẹ wọkọ, tawọn naa ṣe bii ero nibudokọ Ojodu-Berger laajin oru, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta yii.

O ni inu ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Camry ti wọn ṣe lọdun 2005, ni wọn ti bọọlẹ, wọn rọra paaki ọkọ ti nọmba rẹ jẹ KRD-958-HS naa siwaju diẹ, ni wọn ba fẹsẹ rin gba ibudoko naa kọja, ko pẹ sasiko naa ni wọn ka onimọto kan mọ, ti wọn si fibọn gba ọkọ ayọkẹlẹ rẹ nidii onitọhun, Toyota Corolla, to jẹ ẹya tọdun 2003 ni, BDG-946-GZ ni nọmba ọkọ naa.

Ibi ti wọn ti fẹẹ maa ko awọn ọkọ mejeeji sa lọ lawọn ọlọpaa ikọ ayara-bii-aṣa ti wọn n patiroolu ti kẹẹfin wọn ni nnkan bii aago meji aabọ oru ọjọ naa, ni wọn ba sun mọ wọn lati beere ohun ti wọn n wa kiri lọganjọ oru.

Amọ bawọn ẹruuku yii ṣe fura ni wọn bẹ danu, wọn fi ọkọ mejeeji silẹ, wọn ki ere buruku mọlẹ, bẹẹ lawọn ọlọpaa naa gba fi ya wọn, n lọwọ ba tẹ Dayọ, awọn meji yooku raaye sa lọ.

Lasiko iwadii ni Dayọ jẹwọ pe adigunjale lawọn, o ni ọkọ ayọkẹlẹ tawọn bọọlẹ ninu ẹ, adugbo Oworonshoki lawọn ti fibọn gba a lalẹ ọjọ naa, lawọn fi sa wa si agbegbe Ojodu-Berger, pe kawọn tun ṣaajo diẹ si i boya awọn yoo tun ri ọkọ kan gba, ekeji tawọn ji gbe ọhun lọwọ palaba awọn fi segi yii.

Hundeyin ni awọn ti ṣayẹwo loootọ, aṣiri si ti tu pe awọn kọ ni wọn ni mọto ọhun. O lawọn ti taari afurasi ọdaran yii si ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii to lọọrin, bẹẹ lọgaa ikọ RRS, CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ lati tubọ wa gbogbo kọlọfin ibi tawọn to sa lọ yii le fara pamọ si, ki wọn le mu wọn.

Wọn ni kawọn to ba ni awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn fi nọmba rẹ lede yii kan si olu-ileeṣẹ ọlọpaa Eko pẹlu ẹri to daju, ki wọn le gba a pada.

Ni ti Dayọ, irin-ajo rẹ si kootu, nibi ti yoo ti gba idajọ iwa adigunjale to n hu ti bẹrẹ, yoo si balẹ siwaju adajọ laipẹ, bi Hundeyin ṣe wi.

Leave a Reply