Ojo fipa b’ọmọ ọdun marun-un lo pọ n’Idoani, o lojoojumọ lo n gba ọgọrun-un Naira lọwọ oun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ohun ti ọkunrin ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Ojo Akerele, mọ ọn jẹ ti fẹẹ ka a leyin bayii,yẹkinni kan ko si le yẹ ẹ, ọmọkunrin naa yoo ṣẹwọn. Ba a ṣe n kọ iroyin yii, o ti wa nileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹwaa lo pọ niluu Idoani, n’ijọba ibilẹ Ọsẹ.

ALAROYE gbọ pe ọgọrun-un Naira ni Ojo fi tan ọmọbìnrin ta a forukọ bo laṣiiri ọhun wọ ile akọku kan, nibi to ti fi tipatipa ba a sun karakara bii pe agbalagba lo n ṣe ‘kinni’ fun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si akọroyin wa, Alukoro ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni Ojo funra rẹ ti jẹwọ ni teṣan, nigba ti awọn n fọrọ wa a lẹnu wo pe loootọ loun ba ọmọ kekere naa lo pọ.

O ni ọkunrin ọhun sọ ninu alaye rẹ pe ṣe loun mọ-ọn-mọ ba ọmọdebinrin naa lo pọ nitori gbogbo igba loun maa n fun un ni ọgọrun-un Naira, ti ko si figba kan kọ ọ ri.

O ni bi oun tun ṣe fun un lọjọ naa to si tun gba a loun fa a mọra, ti oun si ba a sun dáadáa, nitori ọmọbinrin to ba ti mọ owo o gba gbọdọ mọ ‘kinni’ i ṣe.

Ọdunlami ni dandan ni ki Ojo fojú bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Leave a Reply