Awọn mọlẹbi binu kọ oku ọmọkunrin kan sawọn ọlọpaa lọrun l’Ọrẹ, wọn ni wọn mọ nipa iku ẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ẹni-ori-yọ-o-dile lawọn eeyan fọrọ naa ṣe nigba tawọn ọlọpaa sina ibọn bolẹ lasiko tawọn mọlẹbi oloogbe kan gbe oku rẹ lọọ ka wọn mọ tean wọn to wa niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Awọn mọlẹbi naa ni wọn fẹsun kan awọn ọlọpaa Ọrẹ pe iya ti wọn fi jẹ oloogbe ọhun laarin asiko diẹ to fi wa ninu atimọle wọn lo ṣokunfa iku airotẹlẹ to ku ni kete ti wọn tu u silẹ ni ahamọ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, lawọn agbofinro lọọ ya bo ile-itura kan ti wọn n pe ni Evergreen, eyi to wa lagbegbe Akinjagunla, niluu Ọrẹ, nibi ti wọn ti fi pampẹ ofin gbe oloogbe ọhun atawọn eeyan mi-in.

Ọpọ awọn ti wọn mu ọhun la gbọ pe wọn pada gba beeli ẹni kọọkan wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ogun Naira, koda oni POS kan to wa lẹgbẹẹ tean naa ni wọn n sanwo ọhun fun ki wọn too le gba ominira kuro ninu ahamọ ti wọn wa.

Ni ibamu pẹlu alaye ti ọkan ninu awọn olufẹhonu han naa ṣe fawọn oniroyin, o ni inu ahamọ ni oloogbe ọhun ti bẹrẹ si i ṣaisan latari iya tawọn ọlọpaa fi jẹ ẹ.

O ni nigba tawọn ọlọpaa ṣakiyesi pe ọrọ rẹ ti fẹẹ bọna mi-in yọ ni wọn sare gba beeli rẹ pẹlu ẹẹdẹgbẹta Naira pere lọjọ Iẹgun, Tusidee, dipo ẹgbẹrun lọna ogun Naira ti wọn gba lọwọ awọn yooku.

Lẹyin eyi lo ni awọn ẹbi rẹ sare gbe e lọ sile-iwosan kan fun itọju, nibi to pada ku si lẹyin wakati diẹ to ti wa nibẹ.

Ohun to bi awọn ẹbi oloogbe ọhun ninu ree ti wọn fi lọọ binu kọ oku rẹ si wọn lọrun ni olu ileeẹ awọn ọlọpaa to wa l’Ọrẹ, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa ninu atẹjade to fi sita lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami, ni ọrọ ko ri bẹẹ rara.

Ọdunlami ni awọn eeyan kan lo ta awọn ọlọpaa lolobo pe awọn janduku oloṣelu kan wa ninu otẹẹli naa ti wọn fara pamọ sibẹ, leyii to mu kawọn agbofinro tete lọọ fi pampẹ ofin ko wọn.

Awọn janduku ọhun lo ni wọn ko pẹ ni tesan ti wọn fi gba beeli gbogbo wọn gẹ́gẹ́ bii ilana.

Lẹyinorẹyin lo ni awọn eeyan kan ko ara wọn jọ pẹlu erongba ati waa ṣe ikọlu si tean awọn to wa l’Ọrẹ lori awawi pe awọn n fẹhonu han, ṣugbọn ti awọn agbofinro to wa lẹnu iṣẹ tete tu wọn ka.

Leave a Reply