Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Alaga tẹlẹ fun igbimọ alakooso ileewe olukọni agba niluu Ileṣa, Alagba Kunle Ọdẹyẹmi, ti ṣapejuwe bi Gomina Ademọla Adeleke ṣe da bibẹrẹ Fasiti Ileṣa duro gẹgẹ bii igbiyanju lati lu ọmọ tuntun pa.
Ninu ipade oniroyin kan ti awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC ni ẹkun idibo Guusu Ijeṣa, ṣe l’Ọjọbọ, Tọsidee, ni Ọdẹyẹmi ti sọ pe ko si idi kankan to fi yẹ ki Adeleke da fasiti naa duro.
O ni ohun ti ko tọna ni bi gomina tun ṣe gbe awọn igbimọ amuṣẹya mi-in kalẹ lẹyin ti ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun ti ṣiṣẹ lori abadofin to ni i ṣe pẹlu iṣẹ fasiti naa, ti gomina ana, Oyetọla, si ti buwọ lu u.
Alagba Ọdẹyẹmi ni iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo awọn eeyan ilẹ Ijẹsa pe laarin oṣu diẹ to yẹ ki Fasiti Ileṣa ti maa gba awọn akẹkọọ lẹyin ti ajọ JAMB ati NUC ti fi orukọ rẹ sinu akọsilẹ wọn, ni Adeleke paṣẹ pe ki iṣẹ duro lori ẹ nitori oṣelu.
O ni o yẹ ki Adeleke mọ pe iṣejọba gbọdọ duro lori ohun to ba n mu inu awọn araalu dun, ṣugbọn dipo eyi, iṣejọba ẹtanu ati ti igbẹsan lo n ṣe.
Bakan naa ni kọmiṣanna fun ọrọ igbokegbodo ọkọ ati iṣẹ-odo tẹlẹ l’Ọṣun, Ẹnjinnia Rẹmi Ọmọwaiye, sọ pe ohun ti gomina ṣe lori ọrọ Fasiti Ileṣa naa jẹ nnkan abuku gbaa fawọn eeyan ilu Ileṣa.
O ni ti gomina ba fẹẹ fi oṣelu ṣe ohunkohun, ko yẹ ko jẹ ọrọ fasiti ti gbogbo awọn eeyan Ileṣa ti ni lọkan lati ọdun mẹrinlelogoji sẹyin yii ni yoo fi ṣe e.
Ọmọwaiye fi kun ọrọ rẹ pe Oyetọla ti beere fun atilẹyin ajọ TETFUND lori fasiti naa, bẹẹ ni awọn eeyan ilẹ Ijeṣa ti fi gbogbo akọsilẹ nipa rẹ ṣọwọ si aarẹ tuntun, Asiwaju Bọla Ahmed Tinubu, nitori naa, ko sẹni to le da fasiti yii duro.