Faith Adebọla
Ilu mọ-ọn-ka alaga ẹgbẹ awọn onimọto Eko, to tun jẹ eekan ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) l’Ekoo, Alaaji Musiliu Ayinde Akinsanya, tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, ti sọrọ idunkooko mọ ni m’awọn oludibo nipinlẹ naa, o ni kẹnikẹni ti ko ba ṣetan lati dibo fun ẹgbẹ awọn, iyẹn APC, ki tọhun yaa jokoo sile ẹ, ko ma wulẹ yọju sita rara.
Lede mi-in, kidaa awọn to ba fẹẹ dibo fun APC ni ko jade dibo, lasiko eto idibo sipo gomina ati awọn aṣofin ipinlẹ ti yoo waye jake-jado orileede yii lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii.
MC Oluọmọ sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta yii, nigba to n ba awọn alatilẹyin ẹgbẹ APC kan sọrọ nibi ipade aṣekagba eto ipolongo ibo kan ninu gbọngan nla kan l’Ekoo.
Ninu fidio ati fọto to n ja ranyin lori ayelujara, MC Oluọmọ di ẹrọ abugbẹmu mu, ketekete si lohun rẹ jade bo ṣe n sọ pe:
“A ti bẹ yin, a ti rọ yin, emi dẹ tun fẹẹ bẹ yin ni, dandan kọ ni kẹ ẹ dibo fun wa, amọ tẹ ẹ ba ti mọ pe ẹ o ni i dibo fun wa, ki i ṣe ija. Ẹ sọ fun ara yin, Mama Chukwudi, tẹ ẹ o ba ti ni i dibo fun wa, ẹ jokoo sile yin. Ẹ jokoo sile yin o, ẹ ma jade,” ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bi MC Oluọmọ ṣe n sọrọ ọhun lawọn ti wọn jọ wa niwaju awọn ero ti wọn n ba sọrọ n ṣafikun ohun to sọ, lara wọn si n fi ọwọ fa eti lati ṣafihan pe ki i ṣe ọrọ ṣereṣere o.
Bakan naa lo fi kun un pe ti awọn eeyan naa ba ri i pe ẹkọ ko fẹẹ ṣoju mimu lasiko ibo naa ni agbegbe ti wọn ba wa, ohun ti wọn maa ṣe ti ye wọn. Bẹẹ lo n bi wọn pe ṣẹ ohun ti wọn maa ṣe ti ye wọn, tawọn naa si n dahun pe bẹẹ ni.
Oriṣiiriṣii ọrọ lawọn eeyan ti sọ lori fidio yii. Awọn oniroyin kan ti ta atare fidio naa si Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, ati Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Idowu Owohunwa, lati pe akiyesi awọn agbofinro si ọrọ ihalẹ-mọni ti ọkunrin to jẹ alaga igbimọ to n ṣamojuto awọn gareeji ati ibudokọ ọkọ ero nipinlẹ Eko, Lagos State Parks Management Committee, sọ ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati oludije funpo aarẹ rẹ, Peter Obi ni wọn gbegba oroke ninu eto idibo sipo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji yii, nipinlẹ Eko, eyi si ya ọpọ awọn alatilẹyin APC lẹnu pẹlu bo ṣe jẹ pe ẹgbẹ naa lo ti n bori lawọn idibo to ṣaaju eyi, ti ipinlẹ Eko si jẹ ibugbe oludije wọn, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu.
Wọn lawọn ẹya Igbo to wa nipinlẹ ọhun ni wọn dẹyẹ si APC lasiko idibo naa, latigba naa si ni ọkan-o-jọkan idunkooko mọ ni ati atako to gbona janjan ti n waye laarin awọn ẹgbẹ oṣelu ti yoo kopa ninu eto idibo sipo gomina to wọle de yii.