Faith Adebọla
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, lọwọ awọn ti tẹ mama agbalagba ẹni ọdun mẹtalelaaadọta kan, ti wọn ba awọn iwe ati nnkan eelo idibo INEC lọwọ ẹ.
Hundeyin sọrọ yii ninu ikede kan to fi lede fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, eyi ti i ṣe ọjọ to ṣaaju igba ti eto idibo sipo gomina ati awọn aṣofin ipinlẹ yoo waye kaakiri orileede Naijiria, titi kan ipinlẹ Eko.
Alukoro ni awọn kan ni wọn kẹẹfin mama agbalagba ti wọn ko sọ orukọ rẹ ọhun, ninu ṣọọbu ti wọn ti n fi ẹrọ ṣe ẹda iwe ni nnkan bii aago mẹrin aṣaalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to ṣaaju ni Candos Road, lagbegbe Baruwa, Iyana-Ipaja, nipinlẹ Eko.
Bi wọn ṣe fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ni wọn ti tara ṣaṣa debẹ, wọn si ba mama ọhun bi wọn ṣe wi pẹlu awọn nnkan eelo INEC to n ṣe ẹda rẹ rẹpẹtẹ, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe e lẹyẹ-o-sọka.
Lara nnkan eelo ọhun ni kaadi idanimọ ti awọn oṣiṣẹ INEC maa n wọ sọrun lati fi wọn han bii ojulowo aṣoju wọn atawọn iwe mi-in.
Hundeyin ni: “Ojilelẹẹẹdẹgbẹta ati mẹwaa awọn nnkan eelo ajọ eleto idibo loriṣiiriṣii la ka mọ mama yii lọwọ. A ri ẹrọ kọmputa alaagbeletan to n lo lati fi ṣe ẹda awọn nnkan eelo INEC ọhun, a si ti gba kọmputa naa lọwọ rẹ fun ayẹwo. Nigba ta a bi i leere bi awọn nnkan eelo naa ṣe dọwọ ẹ, ko ri alaye gunmọ kan ṣe, ko si jẹwọ nnkan to fẹẹ lo wọn fun. Iwadii ti jẹ ka mọ pe mama yii ki i ṣe oṣiṣẹ INEC rara. Ni bayii, a ti taari ẹ si ẹka ileeṣẹ awọn ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti, ni Yaba, fun iwadii ijinlẹ. Lẹyin iwadii la maa gbe igbesẹ ofin lori ẹ,” gẹgẹ bo ṣe wi.