Monisọla Saka
Gẹgẹ bi eto idibo gomina atawọn aṣofin ipinlẹ ṣe n lọ lọwọ lawọn ipinlẹ kan lorilẹ-ede Naijiria bayii, oriṣiiriṣii iwa janduku lo n jẹ yọ lawọn agbegbe kaakiri ilẹ Naijiria lasiko eto idbo naa. Akọlu awọn tọọgi oloṣelu yii ko yọ awọn oniroyin silẹ gẹgẹ bi akọroyin Tẹlifiṣan Channels ṣe sọ.
Akọroyin Channels TV kan ṣalaye ohun toju wọn ri lọwọ awọn janduku atawọn agbofinro nileewe alakọọbẹrẹ ijọba to wa laduugbo Folorunshọ Ipesa, Balogun, orile Oshodi, nipinlẹ Eko. O ni, “Wọn o jẹ ka raaye ṣe nnkan kan nigba ta a debẹ, koda nibi ti mo duro si ti mo ti n sọrọ yii, mo ni lati jẹ kawọn ologun yi wa ka ni, nitori awọn ọlọpaa gan-an ko ran wa lọwọ”.
O tọka si obinrin kan to n rin taanu taanu jade lati ibudo idibo naa, pe ọkan lara awọn ti wọn le jade lai jẹ ki wọn ri ibo di ni. Bẹẹ lo darukọ obinrin kan to n jẹ Ajọkẹ, to ṣaaju awọn janduku oloṣelu ti wọn n fa wahala lagbegbe naa. O fi kun un pe ọpẹlọpẹ awọn ologun tawọn lọọ ke si, loun fi ribi sun sẹyin, toun si fi n jabọ ohun to n ṣẹlẹ nibẹ. Yatọ si pe wọn o fẹ oniroyin lagbegbe ibẹ, o loju awọn ti wọn gba laaye lati dibo nibudo idibo ọhun.
O ni, “Nigba ti ki i ṣe pe a wa sibi lati waa ja tabi da ibo wọn ru, ẹ wo bi gbogbo wọn ṣe duro googoogo ti wọn n wo wa pẹlu ibinu, ti ki i baa ṣe pe wọn lẹbọ lẹru, ti wọn si ni nnkan ti wọn fẹẹ ṣe ninu wọn, ki ni iduro wa nibi fẹẹ ṣe fun wọn. Igba ta a ti debi ni wọn ti n halẹ pe a o le duro, wọn ni alami la waa ṣe, ati pe a n ṣiṣẹ fawọn kan ni. Gẹgẹ bẹ ẹ ṣe le ri i, wọn tun ti n kun labẹnu pe ka a jade”.
O ni ṣugbọn awọn dupẹ pe ni kete tawọn ologun de, toun naa lanfaani lati wọnu ileewe alakọọbẹrẹ ti wọn ti n dibo yii, lawọn eeyan ti n ribi ṣe ojuṣe wọn lai foya.