Monisọla Saka
Minisita fun eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed, ti ṣapejuwe eto idibo ọdun 2023 to ṣẹṣẹ pari yii gẹgẹ bii ọkan lara awọn eto idibo to pegede ju lọ, to ti waye lorilẹ-ede Naijiria.
Lai ṣalaye pe, ẹrọ BVAS ti wọn ṣagbekalẹ rẹ ti jẹ ki ọrọ magomago lasiko eto idibo ati ibo adiju dohun igbagbe.
O ni, “Pẹlu nnkan ti mo ṣakiyesi lasiko ibo aarẹ lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ati ibo gomina yii, iyatọ rere ti de ba iṣẹ awọn ajọ eleto idibo ilẹ wa.
“Lai fi igba kan bọ’kan ninu, ibo yii jẹ ọkan lara eyi to daa ju lorilẹ-ede yii. Idi niyi tọrọ awọn eeyan ti mo le pe ni olofo, ti esi idibo aarẹ n bi wọn ninu fi n ba mi lọkan jẹ.
Inu mi dun lati sọ pe pupọ ninu awọn ẹgbẹ oṣelu tinu n bi ti gba ile-ẹjọ lọ, nnkan to daa ju ninu eto idibo yoowu lagbaaye naa si niyẹn. Ẹ jẹ ki kootu ṣedajọ ohun ti ofin ba sọ.
“Lai si ani-ani, ẹrọ BVAS ti wọn gbe wa yii ti yi ọrọ eto idibo wa pada, latara pe eeyan le mọ iye eeyan to forukọ silẹ lati dibo pẹlu ilo BVAS. Bakan naa ni ko ṣee ṣe fẹnikẹni lati dibo lẹẹmeji pẹlu ẹrọ yii, nitori oju eeyan ni ẹrọ yii n gbe keeyan too le tẹka. ”
O tẹsiwaju pe gbogbo ọrọ ti wọn n sọ ta ko ajọ INEC pe yọbọyọbọ leto idibo ti wọn ṣe, lati le da họwuhọwu silẹ ni. O ni akiyesi toun ṣe ni pe ọpọlọpọ awọn ileeṣẹ iroyin n ṣiṣẹ fawọn oludije dupo kan, eyi si tubọ mu ki wọn maa kọ oriṣiiriṣii nnkan to wu wọn lọkan nipa abajade esi idibo ti wọn n gbe sori ẹrọ ayelujara wọn.